Exclusive: Buhari ní àìlera lẹ́mìí, lára, àti lọ́kàn- Obasanjo
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Obasanjo: Buhari ní àìlera lẹ́mìí, lára, àti lọ́kàn.

Oloye Oluṣegun Obasanjọ ba BBC Yorùbá NIKAN sọrọ lori ọrọ Buhari, iṣẹlẹ oun ati Atiku to jẹ igbakeji rẹ nigba kan ri pẹlu iṣẹle Boko Haram.

Obasanjọ sojú abẹ níkòó lórí ọ̀rọ̀ ìkólù Ódè. Baba Iyabọ ṣalaye pé òun kò kabamọ igbesẹ ti oun gbé lori ọrọ Ode.

Oloye Oluṣẹgun Arẹmu Ọbasanjọ to tukọ Naijiria lọdun 1999 si 2007 ṣalaye fun BBC Yorùbá pé nitootọ ni Atiku kò dára pupọ ṣugbọn ó sàn ju Buhari lọ nigba igba.

Ileeṣe aarẹ ti fesi ní àná pe ki Ọbasanjọ lọ sile iwosan fun ayẹwo to yẹ nitori pe o nilo oniṣegun to mọ iṣẹ daadaa.

Ẹ wo ojú òpó yìí ni aago mẹfa owurọ ọla, ọjọ kejilelogun, oṣu kinni, ọdun 2019 fún fidio to ṣalaye ni kikun lori èrò Obasanjọ sí Buhari.

Fun ẹkunrẹrẹ fidio yii, kàn si ojú òpó yii ti o ba fẹ mọ ohun to le jẹ ki IJỌBA TO WA LORI ALEEFA BAYII WỌ INÁ.