Lai Muhammed: Alátakò ti sanwó fún Boko Haram láti ṣèkọlù yíká Nàíjíríà

Minisita Lai Mohammed Image copyright Leadership
Àkọlé àwòrán Lai Mohammed ti fi ọpọlọpọ ẹsun

Agbẹnusọ fún ìjọba apapọ, Lai Mohammed ti ni ijọba ti ni ẹri to daju pe, awọn kan ninu ẹgbẹ oṣẹlu alatako fẹ lo awọn jaduku fun iwa jagidi-jagan lati doju ibo 2019 bolẹ.

Amọ Lai Muhammed ko darukọ awọn ti wọn fura si pe wọn n gbimọ ọtẹ naa ninu ẹgbẹ alatako, bẹẹ si ni ko fi han boya ijọba ti gbe igbesẹ kankan lati fi panpẹ ofin gbe wọn.

Ni ọjọ Aje nigba ti Mohammed ba awọn akọroyin sọrọ, o ni ẹri fi han wipe, wọn ti sanwo fun ikọ Boko Haram lati ṣe awọn ikọlu kakakiri orilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAtiku ní òun kò dènà kí ọ̀dọ́ kankan dupò ààrẹ ní Nàìjíríà

O ni ọgbọn lati doju ijọba bolẹ ki ijọba fidihẹ le wọle ni.

Yatọ si Boko Haram, Mohammed ni ẹri wa pe, ikọ janduku kan ti orukọ rẹ n jẹ Terwase Akwasa, ti gba owo lati ṣe ikọlu ni awọn ipinlẹ Benue, Nasarawa, ati Taraba.

Bẹẹ lo tun ni wọn fẹ lo awọn janduku lati orilẹede Niger Republic lati ṣe ikọlu si awọn eekan ilu kan.

O wa pari ọrọ rẹ pẹlu ileri wipe, ijọba ko ni jẹ ki awọn ete ati ero buruku ẹgbẹ alatako, to fi ẹsun naa kan ko wa si imuṣẹ.