Exclusive: Tí a bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó ń ṣèjọba lọ́wọ́ jáde, wọn yóò wọná - Obasanjo
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Obasanjo: Atiku kìí se Áńgẹ́lì, àmọ́ yóò se dáadáa ní ìlọ́po méjì ju Buhari lọ

Aarẹ tẹlẹ ni orilẹede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, mẹnuba pe, Buhari lo buwọlu ofin pe awọn ọdọ lee dije fun ipo aarẹ, amọ ti oun naa wa n dije lẹni ọdun mẹrindinlọgọrin,

Ọbasanjọ ni ko si ẹni to pe, ni oun se darijin oludije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oselu PDP, Atiku Abubakar, niwọn igba to ti wa bẹbẹ, ki Ọlọrun lee dari awọn ẹsẹ ti oun naa jin oun.

Aarẹ nigba kan ri naa fikun pe, Atiku yoo se daada ni ilọpo meji ju Muhammadu Buhari to wa nipo aarẹ bayii lọ, nitori ẹsẹ awọn eeyan to n dari wa loni gan pọ, ta ba si ni ka tu ẹsẹ wọn sita, wọn yoo wọna, yatọ si pe wọn yoo wọ ẹwọn, wọn yoo tun wọ ina.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọbasanjọ ni, Buhari ko ni igbẹkẹle ninu ẹya miran lati baa sisẹ, ju awọn ibatan rẹ nidi iya ati baba lọ.

O fikun pe, niwọn igba ti Buhari ko ti ni igbẹkẹle ninu ẹya miran, ko yẹ ko beere ibo lọwọ wọn, tori bu fun mi, ki n bu fun ọ ni ọpọlọ nke loke odo.

Ẹwẹ, ijọba apapọ ti fesi si awọn ẹsun ti Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ sọ nipa ijọba Muhammadu Buhari .

Amugbalẹgbẹ Buhari feto iroyin, Garba Shehu, nigba to n fesi sawọn ẹsun naa naa ni irọ lasan ni Ọbasanjọ n pa lori awọn ẹsun naa.

O fikun pe Ọbasanjọ n jowu ni, ti ọpọlọ rẹ ko si da pe mọ, bẹẹ lo ni Ọbasanjọ nilo lati l ri dokita.