Obasanjo kò mọ ohun tó ń se mọ́, ẹ máṣe tẹ́tí si ọ̀rọ̀ rẹ̀ - Ore Falomo
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Falomo: Ó yẹ kí Obasanjo ti jẹ asaájú Yorùbá, àmọ́ kò leè jẹ́

Dokita Ore Falomo ati Sẹnatọ Fẹmi Okurounmu, tii wọn jẹ agbaagba nilẹ Yoruba, ti fesi si awọn koko ọrọ ti Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ sọ nipa isejọba Buhari.

Lero ti Ọrẹ Falọmọ, agba ti n da Ọbasanjo laamu, ko si yẹ ka tẹti si awọn ọrọ rẹ mọ.

Falọmọ ni Ọbasanjọ ko mọ ohun to n se mọ, idi si ree ti a ko se fi jẹ asaaju ilẹ Yoruba lati ọjọ pipẹ wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa rọ Obasanjọ lati tọrọ idarijin lọdọ Ọlọrun fun bo se da iran Yoruba ati Oloogbe MKO Abiola, pẹlu afikun pe, ko lẹtọ fun Ọbasanjọ lati maa sọ pe Atiku ṣẹ oun.

Nigba to n sọ ero rẹ lori ọrọ ti Ọbasanjọ sọ nipa isejọba Muhammadu Buhari, Sẹnatọ Fẹmi Okurounmu sọ pe, ko si irọ kankan ninu awọn ọrọ ti Ọbasanjọ sọ sita, ija ilu si lo n gbe.

Okunrounmu ni ko bojumu to ki Buhari maa yan ibatan rẹ nikan sipo lai nigbẹkẹle ninu ẹya miran,

Bakan naa lo faramọ ọrọ Ọbasanjọ pe isọwọsisẹ ajọ eleto idibo Inec mu ifura lọwọ.