Àtúntò FSARS: Àwọn ọmọ Nàìjíríà bẹ̀nu ẹ̀tẹ́ lu àtúntò FSARS

Aworan ọlọpa SARS kan Image copyright @OfficialSARS
Àkọlé àwòrán Àwọn aláṣẹ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìlànà iṣẹ́ ikọ̀ ọlọ́pàá kògbérégbè FSARS kò fi ààyè ìrégbè sílẹ̀ fún wọn

Eero awọn ọmọ orilẹede Naijiria ṣọtọọtọ si bi ọga ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Mohammed Adamu ṣe da awọn ọlọpaa FSARS pada, ti ọpọlọpọ si n fapa janu lori ẹrọ ayelujara.

Bi awọn kan ṣe n gboriyin fun igbesẹ yii ni awọn kan gbagbọ pe yoo da iwa ifiyajẹni ati inilara to googo laarin awọn oṣiṣẹ SARS pada saarin ilu.

Tẹlẹ ni Ọga ọlọpaa ana, Ibrahim Idris gbe ẹka ileeṣẹ ọlọaa SARS sabẹ igbakeji Ọga Agba Ọlọpaa. Ṣugbọn ni bayii, awọn kọmisana ọlọpaa l'awọn ipinlẹ to wa lorilẹede yii ni yoo maa mojuto awọn ọlọpaa SARS.

Ǹjẹ́ o rí ọlọ́pàá SARS tó ń hùwà àìtọ́ láwùjọ?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAAUA; Ọ̀pọ̀ ìgbà ni SARS ma ń lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì wa

Ṣaaju asiko yii ni awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti n pe fun opin si iṣẹ awọn ọlọpaa SARS pẹlu ami ipolongo #EndSARS nitori awọn ẹsun ifiyajẹni ati titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ ti wọn fi n kan wọn.

Lara awọn to ti bu ẹnu ẹtẹ lu igbesẹ ọga ọlọpaa ni ajọ ajafẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amnesty International, ẹka ti Naijiria.

Ajọ naa loju opo Twitter rẹ sọ pe atunto ti ọga ọlọpaa kede gbọdọ tumọ si fifi opin si ifiyajẹni, fifini si ihamọ lọna aitọ, iwa ilọnilọwọgba, ati iṣekupani 'ti awọn oṣiṣẹ SARS ti hu jakejado orilẹede Naijiria fun ọpọlọpọ ọdun.

Bakan naa ni awọn kan ni asiko tun ti to lati ji ipolongo #EndSARS dide pada nitori igbesẹ ti ọga ọlọpaa gbe yii, nitori pe fifi opin si SARS patapata ni awọn ọmọ Naijiria n fẹ.

Lọjọ Aje ni ọga agba ọlọpaa kede pe igbesẹ atunto ti oun kede rẹ jẹ ọna lati mu atunṣe ba ajọ SARS.

Àfojúsùn àtúntò FSARS ni láti mú àgbéga bá iṣẹ́ ọlọ́pàá- IG

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSARS: Awọn ará ìlú fi ẹ̀rí síta nípa ìrírí wọn