Àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ lórí níní adarí tó ju ọdún 70 ló lọ́ja orí #BBCNigeria2019
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

'Àgba tóri ẹ bá pé ni Naijiria nílò lásìkò yìí'

Baba 70 ti dàgbà jú fún Naijiria ni èrò àwọn mii.

Àwọn ọmọ Naijiria sọrọ lori àwọn agbalagba ti wọn n dije dupo aarẹ ni Naijiria lasiko yii.

Bi awọn kan ṣe ni ìrírí kọja ẹgbẹ abewú naa ni awọn mii ni asiko ti to ki awọn arugbo lọ fadagba ètò rọ sibi kan.

Awọn ọmọ Naijiria mii ko náání pé wọn ti lé laadọrin ọdun nitori ibanujẹ lọjọ ori, ipo lagba.

Awọn kan gba pe asiko ti to ki Naijiria fawọn ọdọ laaye lati dupo aarẹ ki akukọ tuntun le kọ fun igbadun ara ilu.

Bẹẹ lawọn mii ni ọrọ Naijiria jẹ atari ajanaku ti kii ṣe ẹru ọmọde ti ẹnikẹni le dagbe pẹlu irun dudu.

Ni ipari, gbogbo wọn ṣalaye fun BBC pé ibẹru Olorun lo ṣe pataki julọ lookan aya olori rere lainii fiṣe ọjọ ori rẹ. Wọn sọrọ lori pataki nini ifẹ awọn ara ilu ti kaluku n dari.

Opolopo gbà pé ki àwọn olori Naijiria yàgò fún ìwà Tani o mumi àti kẹnimani ninu eto idibo 2019 to m bọ yii.