Fayemi: Ẹ̀sùn àjẹbánu àti lílo owó básubàsu la fi kàn wọn

Kayode Fayemi Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán Awọn tí ìfipòsílẹ̀ náà kàn ni adarí ilé ẹ̀kọ́ fásitì EKSU, adarí ilé ìwòsàn tó wà ní ìpínlẹ̀ Ekiti, EKSUTH.

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayode Fayemi ti fasẹ si pe ki adari fasiti ipinlẹ Ekiti, EKSU, Ọjọgbọn Samuel Oye Bandele.

Awọn miran ti wọn tun jawe lọ gbe ile rẹ fun ni, Adari ile iwosan ẹkọsẹ isegun fasiti naa, KSUTH, Kolawole Ogundipe ati adari ile ẹkọ giga to wa ni Ikẹrẹ-Ekiti, Ọjọgbọn Mojisola Oyaraqua.

Igbimọ majẹ ko bajẹ ni ipinlẹ naa, lasiko ipade wọn ni awọn rọ gomina lati gbe igbese iyọni nipo naa, lẹyin ti wọn se abẹwo si awọn ọgba ile-ẹko giga ọhun ati si awọn ile-isẹ ti ọrọ naa kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMurphy Elégungun Rọba: Mo fẹ́ di ẹnití egungun rẹ rọ jùlọ ní àgbáyé

Ẹsun ajẹbanu ati lilo owo ile iwe basubasu, ni wọn fi kan awọn adari ile iwe giga.