Murphy Elégungun Rọba: Mo fẹ́ di ẹnití egungun rẹ̀ rọ̀ jùlọ ní àgbáyé

Murphy Elégungun Rọba: Mo fẹ́ di ẹnití egungun rẹ̀ rọ̀ jùlọ ní àgbáyé

Ọba afinidara ni Ọlọrun, bo se da dudu, naa lo da funfun, o da ẹni ti eegun rẹ le koko, to si tun da ẹni ti eegun rẹ rọ bii rọba.

Ọkan ninu awọn akanda ẹda to se ara ọtọ ni Murphy jẹ, nitori bi Oluwa se fi egungun to rọ bii rọba jinki rẹ.

Murphy, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni, afojusun oun ni lati jẹ ẹniti egungun rẹ yoo rọ julọ lagbaye, lati maa ka a bo se wu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni oun lee ka bii ejo ati ẹja, eyi si lo gba ẹmi oun lọwọ ewu nigba ti oun ja bọ lati ori oke bọ wa silẹ.

Ọkunrin elegungun ejo naa ni ko nkan ti oun fẹ ka bii rẹ, ti oun ko lee se.