Danjuma: Ète ń lọ láti dá wàhálà sílẹ̀ láwọn ìpínlẹ̀ kan torí mọ̀kàrúrù ìbò

Theophilus Danjuma Image copyright @tarabavoices

Minisita tẹlẹ feto aabo, Ajagunfẹyinti Theophilus Danjuma, ti ke gbajare lori ete awọn eeyan kan lati se mọkaruru ibo gbogbo gboo to n bọ.

Danjuma, ẹni to ke gbajare yii lasiko to sefilọlẹ ibudo kan nipinlẹ Taraba, tun fi kun pe, eto iselu taa n se ni Naijiria luko pupọ, ti ko si laju rara.

Bakan naa lo sisọ loju rẹ pe, ete kan tun ti n lọ lati da wahala silẹ lawọn ipinlẹ kan lorilẹede yii, afojusun igbesẹ yii si ni lati dabaru esi ibo ti yoo wa lawọn ipinlẹ ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMurphy Elégungun Rọba: Mo fẹ́ di ẹnití egungun rẹ rọ jùlọ ní àgbáyé

Danjuma wa fi ewe ọmọ mọ awọn eeyan ipinlẹ Taraba leti pe, ki wọn raga bo ibo ti wọn ba di, ki awọn alaparutu ma baa ri ji.

"A gbọdọ sisẹ kara ki alaafia lee jọba, yatọ si pe a fi orukọ silẹ, taa si tun gba kaadi idibo alalopẹ wa.

Ko si idi fun wa lati maa doju ija kọ ara wa nitori wọn yoo lo awọn ọlọpaa ati sọja lati da wa riboribo, ti wọn yoo si raye ji ibo wa."

Image copyright @tarabavoices

Minisita tẹlẹ naa tun fikun pe, awọn ti wọn n pete idaluru yii mọ pe awọn ko lee bori ibo ti alaafia ba n jọba.

O si rọ awọn eeyan rẹ lati mase ta ibo wọn, tori yoo da bii igba ti wọn n ta ogun ibi wọn ni, ti wọn ba se bẹẹ.