Wọ́n fi iṣẹ́ tàn ań wá sí Eko, kí wọ́n tó fun ní HIV
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

HIV kò sí nínú àfojúsùn ọmọdébìnrin yìí nígbà tó gbà láti wá sí ìlú Eko

Orilẹ-ede Naijiria lo ni awọn eniyan ti wọn fi ipa tabi ọgbọn ẹ̀wẹ́ mu wọ oko ẹru igbalode julọ ni Afrika.

Gẹgẹ bi akọsilẹ iye awọn to wa l'oko ẹru l'agbaye, awọn to to miliọnu kan ati irinwo ẹgbẹrun lo n gbe ni oko ẹru igbalode ni Naijiria.

Akọroyin BBC, Kunle Falayi ṣe iwadi igbeaye ọmọdebinrin, ẹni ogun ọdun kan ti wọn fi ọgbọn ẹwẹ mu kuro ni abule wọn ni ipinlẹ Akwa Ibom.

Wọn muu wa si ilu Eko pẹlu ileri pe igbe aye rẹ yoo dara sii ṣugbọn ọrọ ba ẹyin yọ nigba ti o kó arun HIV lẹnu iṣẹ aṣẹwo ti wọn fi si.

Producer: Kunle Falayi

Video: Chukwuemeka Anyikwa and Dan Ikpoyi