Day 23: Ikẹnnẹ ṣááju àti lẹ́yìn ìwọlé Ọṣinbajo sípò #BBCNigeria2019
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Osinbajo: Ikẹnnẹ yẹ kó jẹ́ Mẹ́kà òṣèlú ni

Ọpọlọpọ ló gbà pé ilẹ̀ Wúrà ni Ikenne jẹ ninu oṣelu Naijiria.

Ikẹnnẹ jẹ ọkan lára àwọn ijọba ibilẹ to wa ni ẹkun Rẹmọ ní ipinlẹ Ogun ni ẹkun Guusu-iwọ oorun Naijiria.

Awọn eekan ninu oṣelu ni wọn ti nii ṣe pẹlu Ikẹnnẹ bẹrẹ lati Oloye Obafemi Awolowo ti gbogbo eyan kà sí baba nla iran Yoruba ninu iṣelu Naijiria.

Oloye HID Awolọwọ, Omowe Tai Solarin tó jẹ ogbontarigi olukọni ajafẹtọ ọmọniyan àti Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo to jẹ igbakeji aarẹ Naijiria lati ọdun 2015.

BBC Yorùbá ṣabẹwo si ijọba ibilẹ Ikẹnnẹ lati mọ boya àwọn eniyan ijọba ibilẹ yii n janfaani igbakeji aarẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn ogidi ọmọ Ikẹnnẹ.

Ọpọlọpọ wọn ló kan sadankata sigbakeji aarẹ pé o ṣiṣẹ silu Ikenne bii kikọ ọja tuntun, lila gọta, kikọ ile iwe.

Sugbọn ó kù nibọn n ró ni wọn fi ṣẹ pé oorun to ku ṣi to aṣo lati gbẹ ki Oṣinbajo le wa pari awọn iṣe to ku.

Àwọn kan ni wọn n fẹ ipinlẹ Ijẹbu, ọpọ n fẹ atunṣe soju opopona gbogbo ti kò dara ṣugbọn ariwo kikọ ilé iṣẹ tuntun ni awọn iyalọja n pa ki ọja wọn le maa tà ti ero ba pọ lati fi dẹkun airiṣẹṣe awọn ọdọ.

Oba Adeyinka Onakade -Moruwafu1 nilu Ikẹnnẹ naa ba BBC sọrọ lori ipa Osinbajo nilu rẹ pẹlu imọran fun gbogbo oloṣelu pé ti Ẹde ba bajẹ, ẹ̀ẹ̀dẹ̀ leeyan n pada si, pé ki onikaluku má gbagbe orisun rẹ̀.

Gbogbo ìran Yoruba lo gbà pé aríṣe ni aríkà; bẹẹ aríkà ni baba ìrègún ni ọrọ ile aye jẹ.

Ohunkohun ti onikaluku ba ṣe loni, ọrọ itan ni yoo da lọla.

Awọn eniyan Ikenne kan ṣafiwe awọn ọmọ Ogun to ti goke ọla sẹyin ṣugbọn ti wọn ko ṣe nkankan fún ìlú, ipinlẹ ati iran wọn lapapọ.