Ò ti pẹ́ jù fún Ezekwesili láti yọwọ́, orúkọ ẹgbẹ́ rẹ̀ ACPN yóo hàn lórí ìwé ìdìbò #BBCNigeria2019

Image copyright @Oby
Àkọlé àwòrán O ti to oṣu mẹta ti a ti n sọrọ pọ lori igbesẹ mi yii

Lẹ́yin wakati melòó kan ti oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ́ oṣelu ACPN fi han pe oun ti jawọ ninu idije naa, ajọ eleto Idibo (INEC) ni o ti pẹ́ ju lati gbe igbesẹ naa.

Agbẹnusọ ajọ naa kan Oluwole Osaze-Uzzi ni INEC ko tun le pa orukọ ẹgbẹ oṣelu rẹ̀ ACPN to ti wa lori iwe idibo mọ

Oby ṣe ikede lori ikanni twitter rẹ pé oun yọwọ ki oun lè pa ọkan pọ láti fopin si ijẹgaba ẹgbẹ APC ati PDP ninu iṣelu Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEzekwesili: Mo fẹ́ sọ Nàíjíríà di ilẹ̀ tí àǹfàní ọgbọọgba wà

Oby Ezekwesili ni oun gbé igbesẹ yii ki oun le fi ọgbọn kun ọgbọn fun awọn oludije to ku lati jọ di òṣùṣu ọwọ̀ to máa ra iṣejọba Tiwa-n-Tiwa padà ni Naijiria ni.

O ni oun yoo maa figba gbogbo fọn rere rẹ pé ijọba Naijiria yẹ ko dara ju gbogbo eyi ti ẹgbẹ PDP ati APC n ṣe yii.

Fẹla Durotoye ọkan lára awọn oludije fún ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu ANN naa sọrọ lori ifọwọsowọpọ ti àwọn ẹgbẹ oṣelu keekeeke n gbiyanju lati ṣe ki wọn fi le bori ninu idibo 2019.

Oby Ezekwesili ni nitootọ ni igbesẹ oun yii ko tẹ gbogbo ọmọ ẹgbẹ Allied Congress Party of Nigeria (ACPN) lọrun, ṣugbọn oun ti ṣetan lati fipinnu ijọba rere ni Naijiria hàn dipo erongba ọkan oun gẹgẹ bii oludije

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEzekwesili: Àfojúsùn mi ni láti mú ààbò ẹ̀mí ọmọ Nàíjíríà ní ọ̀kúnkúndùn

Oby gba awọn eniyan niyanju lati ma ro idagbasoke Naijiria pin nitori pe ohun ti a ba jọ ja fun lo n mu itẹsiwaju wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption2019 Elections: Èrò àwọn ọmọ Nàíjíríà se ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lóri ètó àlùfáà tàbí ìmámù lásìkò ìbò
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionìpàdé ìtagbangba ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò gomina ní ìpínlẹ̀ Eko.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsinbajo: Ikẹnnẹ yẹ kó jẹ́ Mẹ́kà òṣèlú ni