Miliọnu kan naira nileeṣẹ to ba fiya jẹ àkàndá ẹ̀dá a san lówó ìtanràn

Ẹni to n fi igi rin Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹnikẹni ko gbọdọ dẹyẹ si akanda ẹda ni ibudo idikọ, ati wi pe awọn to ni ileeṣẹ irinna gbọdọ ṣeto to yẹ fun awọn ti ko le rin

Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu ofin ti yoo maa sọ didẹyẹsi awọn akanda ẹda di iwa ọdaran ni Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌyá àkàndá ẹ̀dá: Àwọn ẹbí mi fẹ́ kí n pa ọmọ mi torí ó jẹ́ àkàndá ẹ̀dá

Aṣoju aarẹ nile aṣofin, Ita Enang to fi ikede naa sita ṣalaye fun awọn akọroyin lalẹ Ọjọru pe ofin tuntun ọhun, ni yoo ma rii daju pe awọn ileeṣẹ tabi ẹnikọọkan to ba hu iwa ti ko tọ si akanda ẹda jẹ iya to tọ labẹ ofin.

Ohun Marun un too ni lati mọ nipa ofin to da abo bo awọn akanda

  • Ẹnikẹni to ba hu iwa ti ko tọ si akanda yoo fi ẹwọn oṣu mẹfa gbara tabi ko san faani ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira; bi o ba wa ṣe ile iṣẹ lo dẹyẹ si akanda, miliọnu kan naira ni yoo fi gbara.
  • Gbogbo ile iṣẹ to jẹ ti ijọba yoo fi aaye ida marun un iṣẹ silẹ fun awọn akanda.
  • Ọdun marun un ni ijọba fun awọn ile isẹ nigboro tabi nkan irina bii ọkọ ati baalu gbudọ tun ọna wọn ṣe ki awọn akanda le maa ri aye wọle.
  • Bakan naa, abala ofin yii sọ wi pe ki awọn ile iṣẹ to kọ ile si igboro, ki wọn kọkọ wo alakalẹ ile naa lati ri i daju pe ko le si idiwọ fun awọn akanda.
  • Ọdun mejidinlogun sẹyin ni abadofin fun awọn akanda yii ti wa niwaju ile igbimọ aṣofin iyẹn ọdun 1999 ti awọn aṣofin kọkọ da a labaa lakoko iṣejọba aarẹ ana, Oluṣẹgun Ọbasanjọ. Ki aarẹ Muhammadu Buhari to pada wa buwọlu u, o ti gba iwaju ile aṣofin kọja nigba mẹrin.

Labẹ ofin tuntun naa, ileeṣẹ to ba jẹbi ẹsun fifi iya jẹ akanda ẹda kankan yoo san miliọnu kan Naira gẹgẹ bi owo itanran, ti ẹnikan yoo si san ọgọrun un ẹgbẹrun Naira tabi lọ si ẹwọn oṣu mẹfa pẹlu rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOgundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́

Bakan naa ni ofin naa yoo fi aaye ọdun marun un silẹ fun awọn ile to wa fun lilo araalu lati ṣe atunṣe ti yoo mu ki awọn akanda ẹda, to fi mọ awọn to n lo kẹẹkẹ lara wọn lati le wọ awọn ile bẹ pẹlu irọrun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYorùbá gbà pé òrìṣà bí ìyá kò sí!

Ẹnikẹni to ba fẹ kọ ile ti araalu yoo maa lo(ile ounjẹ, ileewosan, ile itaja ati bẹẹbẹ lọ), awọn ajọ to wa fun ile kikọ gbọdọ ṣayẹwo ilana ti wsn la kalẹ fun kikọ ile naa lati ri daju pe o pa ofin ọhun mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption2016 ni Angel kọ́kọ́ gbé àwo orin rẹ̀ síta láti fi bèrè ìdí tí òun fi yàtọ̀

Ati wi pe oṣiṣẹ tabi ileeṣẹ ijọba to ba buwọlu kikọ ile ti ko pa ofin naa mọ yoo san miliọnu kan Naira owo itanran, fi ẹwọn ọdun meji jura tabi mejeeji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMurphy Elégungun Rọba: Mo fẹ́ di ẹnití egungun rẹ rọ jùlọ ní àgbáyé

"Ẹnikẹni ko gbọdọ dẹyẹ si akanda ẹda ni ibudo idikọ, awọn to ni ileeṣẹ irinna gbọdọ ṣeto to yẹ fun awọn ti ko le rin, rina tabi gbọrọ, ati awọn akanda to ku. Eyi wa fun awọn to n ṣeto irinna loju omi, ofurufu ati oju'rin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIpenija ojú kò di Ademola lọ́wọ́ láti kẹkọọ gboye

"Ẹwẹ, ofin naa fi mulẹ pe gbogbo ileeṣẹ ijọba gbọdọ fi aaye ida maarun silẹ fun awọn akanda ẹda ninu eto igbanisiṣẹ wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌmọ̀bìnrin tí wọ̀n bí láì ní ẹsẹ̀: Ati kekere ni ìyá mí ti kọ̀mí sílẹ̀