Àwọn nkan márùn ún tó gbajúmọ̀ nípa ìlú abínibí Buhari #BBCNigeria2019

daura
Àkọlé àwòrán,

Kẹtẹkẹtẹ jẹ ọkan lara àwọn nkan irinna to wọpọ ni Daura

Ipinlẹ Katsina, ni ẹkùn Iwọ oorun Ariwa Naijiria ni ilu Daura wa. O si pa aala pẹlu orilẹ-ede Niger lati Damagaram.

Bakan naa lo pa ààlà pẹlu ipinlẹ Jigawa ni ilu Kazaure.

Daura ni ilu to ti pẹ ju ninu itan ẹya Hausa, koda, awọn oluwadii kan tilẹ gbagbọ pe Daura ni orisun ede Hausa.

Daura jẹ ilu abinibi Aarẹ Muhammadu Buhari, ibẹ lo si ti lo eyi to pọju ninu ọjọ aye rẹ.

BBC ṣe akọsilẹ awọn nkan marun un to ṣe koko, to si sọ ilu Daura di gbaju-gbaja kaakiri agbaye.

Àkọlé àwòrán,

Ibrahim Issa to n figbadun ṣayọ

1. Ìtàn ilu naa

Nkan akọkọ ti Daura gbajumọ fun ni ìtàn iṣẹdalẹ ilu naa.

Akọsilẹ ìtan tilẹ sọ pe Daura ni orisun ede Hausa ati awọn ẹya Hausa. Botilẹ jẹ wi pe awọn onimọ kan ko faramọ eyi.

Ṣugbọn ohun to daju ni pe, Daura jẹ ọkan lara awọn ilu meje to jẹ orisun ẹya Hausa.

Oriṣiriṣi ọba ati iṣakoso to ti ara Ayaba Daurama jade lo ti jẹ ni Daura titi di oni. Bakan naa ni ilu naa ni awọn ilẹkun abalaye ati ilu olodi, to wọpọ ni ọpọlọpọ ilu to wa ni ilẹ Hausa.

Àkọlé fídíò,

'A máa ń bẹ́ orí ẹni tó bá gbé imọlẹ̀ ọdún ìjẹṣu tó bá ṣubú ni'

2. Daurama

A ko le sọrọ nipa ilu Daura, lai mẹnuba Ayaba Daurama - oun ni Ọbabinrin to jẹ kẹyin ni Daura.

Ìtan fihan pe Daurama ni Ọbabinrin to wa lori itẹ lasiko ti akọni igbanni, Bayajidda lọ si Daura, to si pa ejo nla to n ba awọn araalu l'ẹru. Daurama fẹ ẹ fun iwa akikanju rẹ.

Daurama lo bi awọn ọmọkunrin meje to pilẹ awọn ipinlẹ ẹya Hausa mejeeje - Bawo, Biram, Kano, Katsina, Zazzau, Gobir and Rano.

Ìtan ẹya Hausa kò pe, lai si ọrọ Ọbabinrin Daurama ninu rẹ.

3. Bayajidda

Ọpọlọpọ eniyan gbagbọ pe orilẹ-ede Baghdad ni orisun Bayajidda, ko to o di pe o wa si Borno nibi to gbe fun igba diẹ. Lẹyin naa lo lọ si Daura.

Asiko naa lo ṣawari ìdà to fi pa ejo nla ti ko jẹ ki awọn araalu Daura o raaye pọn omi ninu kanga Kusugu.

Lẹyin naa, Ọbabinrin Daurama fẹ Bayajidda l'ọkọ. "Daurama si di iya nla ẹya Hausa ati awọn eniyan rẹ."

Ṣugbọn, awọn onimọ kan bi i Muhammad Tahar Adama (Baba Impossible) ati Ọjọgbọn Uba Adamu sọ pe ìtàn naa kii ṣe otitọ.

Àkọlé fídíò,

Obasanjo: Atiku kìí se Áńgẹ́lì, àmọ́ yóò se dáadáa ní ìlọ́po méjì ju Buhari lọ

4. Kusugu

Nigba ti Bayajidda de si ilu Daura, o de si ile obirin arugbo kan, Ayyana. O si beere fun omi, ṣugbọn o sọ fun un pe oun ko ni, nitori pe ejo kan fi inu kanga ti awọn n pọn ṣe ibugbe.

Ọjọ Ẹti nikan ni ejo naa maa n fi aaye gba omi pipọn.

Ni Bayajidda ba gba gooro ipọnmi kan lọwọ rẹ, o si lọ si ibi ti kanga naa wa. O pa ejo yii, o bẹ ẹ lori, o si pọn omi jade ninu kanga.

Àkọlé fídíò,

'Ó ṣojú mi kòró, ẹ wọ bí ìgbà ayé Bàbá Fagunwa ṣe rí'

Nitori naa ni Ọbabinrin Daurama ṣe fẹ ẹ.

Kanga naa ṣi wa nilu Daura titi di oni, wọn si n pọn omi ninu rẹ. Ṣugbọn, o ti di nkan ti awọn eniyan n rin irinajo igbafẹ lati wo.

Ìtan ilu Daura ko pe rara lai sọ nipa kanga Kusugu.

Àkọlé fídíò,

Bimpe: Èèyàn bíi tiyín ni àfín, ẹ dẹ́kun dídẹ́yẹsí àfín

5. Awọn olokiki eniyan

Yatọ si wi pe ìtàn fi Daura si ipo pataki ni ilẹ Hausa ati Naijiria, Daura tun ni ọpọlọpọ awọn olokiki eniyan.

Ọgagun Muhammadu Buhari: Olori ijọba ologun nigba kan ni Naijiria, to si tun jẹ aarẹ lọwọlọwọ. Ọmọ ilu Daura ni, ibẹ lo si ti lo pupọ ninu igbesi aye rẹ.

O ṣoro fun ẹnikẹni to mọ Buhari lati ma mọ pe ọmọ bibi ilu Daura ni, nitori pe ibẹ lo ti maa n ṣe ọpọ ayẹyẹ rẹ.

O ni ile, oko, ẹbi ati ọrẹ nibẹ.

Àkọlé fídíò,

Ogundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́

Àkọlé fídíò,

2019 Elections: Èrò àwọn ọmọ Nàíjíríà se ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lóri ètó àlùfáà tàbí ìmámù lásìkò ìbò

Ọba Umar Faruk Umar: Lọwọlọwọ, oun ni Emir ilu Daura. Oun si ni Emir ọgọta to jẹ ni Daura. Gbaju-gbaja ni kaakiri apa Ariwa Naijiria.

Alhaji Usman Daura: Oun ni olori ẹṣọ alaabo fun Aarẹ Shehu Shagari, Ọgagun Muhammadu Buhari ati Ọgagun Ibrahim Babangida laarin ọdun 1981 si 1989.

Sani Ahmed Daura: Gomina akọkọ to jẹ ni ipinlẹ Yobe lọdun 1991 si 1998.

Sani Zangon Daura: Minisita fun iṣẹ agbẹ ati idagbasoke igberiko laarin ọdun 1999 si 2000, ati Minisita fun ayika lọdun 2000 si 2001.

Ja'afar Mahmud Adam: Gbaju-gbaja onimọ ẹsin Islam ni, o si lo pupọ ninu igbesi aye rẹ ni ilu Kano. Ṣugbọn ọpọ mọ pe ilu Daura lo ti wa.

Lawal Musa Daura: Ọga agba nigba kan fun ajọ alaabo DSS.

Ambassador Mamman Daura: O ti ṣe aṣoju orilẹede Naijiria si Uganda, Saudi Arabia, South Korea, Belgium ati Cameroon.

Àkọlé àwòrán,

Awọn eekan lo ti jade lati ilu Daura sẹyin

Akanṣe Ayẹyẹ

Àkọlé àwòrán,

Ilu Daura ti di orukọ ilumọọka kaakiri lẹyin ti Buhari di aarẹ lẹẹkeji

Ayẹyẹ pataki nilẹ Hausa, Durbar, maa n waye lasiko ọdun ileya. O si maa n larinrin. Igbagbọ wa pe ilu Daura lo ti bẹrẹ.

Awọn olukopa nibi ayẹyẹ naa sọ pe asiko Bayajjida lo bẹrẹ lati le mu ki iṣọkan wa laarin awọn Ọba ilẹ Hausa, ṣugbọn atunṣe ba a lẹyin ti ẹsin Islam de.

Àkọlé fídíò,

Ọ̀tọ̀ ni nkan tí wọ́n sọ fún ẹbí rẹ̀, iṣẹ́ aṣẹ́wó ni wọ́n fi n ṣe