Ezekwesili sọ ìdí tí ko fi dídu ipò sílẹ̀

Oby Ezekwesili Image copyright @SHEWENZI
Àkọlé àwòrán Ezekwesili tó jẹ́ ọ̀kan lára olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ Bring Back our Girls #BBOG ní ẹni tó mọ̀ nípa mẹ̀kúnù ni òun yàn ní igbákejì.

Minisita tẹlẹ ri fun eto ẹkọ, ọmọwe Obiageli Ezekwesili ti da ẹbi le ohun ti ẹgbẹ oṣelu rẹ sọ si bi o ṣe yọ ara rẹ kuro lara awọn oludije fun ipo aarẹ.

Ni tirẹ, o ni oun pinu lati tete fi didu ipo naa ji lati le gbe opo iwa ire rẹ ro.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin ló ni ilé àti àdúgbò fún ìdí èyí wọ́n lè ṣe ìlú dáadáa'

"Orilẹede Naijiria nilo ilana ọtun ati awọn adari to kun oju osuwọn to si to gbangba sun lọyẹ. Mo si lero tẹlẹ pe ACPN pawọpọ pẹlu mi lati ṣe eyi afi igba ti wọn pa awọ da.

Igba ti ibi a kori si ti wa di ọtọọtọ lo fa sababi bi mo ṣe yẹra fun ere ije didupo aarẹ labẹ asia wọn. O tẹnu mọ ọ.

Esi Oby Ezekwesili jẹ jade ni orilẹede Mexico nibi ipade Albert Einstein's Genius Visionaries to dara pọ mọ ninu ọrọ rẹ to sọ wi pe "ko si irọ kankan to le di oṣelu ọtun lọwọ.

"Ni ti ọrọ ibanilorukọ jẹ ti adari ẹgbẹ ACPN sọ nipa mi, mo fẹ ki awọn ọmọ Naijiria mọ pe ko si ẹyọ ootọ kankan ninu gbogbo rẹ.

Ezekwesili ni ohun ko tii le fesi si ifọrọwanilẹnuwo kankan afiti oun ba pada de si orilẹede Naijiria ti oun yoo si pe ipade oniroyin lati ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ.