Ọjọ́ ńlá ní DR Congo, bí ààrẹ tuntun ṣe gbaṣẹ́

Felix Tshisekedi Image copyright AFP

Aarẹ tuntun ti gba ijọba ni orilẹede DR Congo. Orukọ rẹ ni Félix Tshisekedi.

O sọ fun awọn ọgọọrọ alatilẹyin rẹ nile ijọba ni Kinshasa wi pe oun yoo rii pe iṣọkan wa ni orilẹede naa.

Eyi to yani lẹnu ju ni oun to ṣẹlẹ si aarẹ tuntun naa nigba ti wọn n bura fun wọle ti o si n sọ ọrọ akọkọ rẹ.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Ṣe ni ko le sọrọ daradara ti o si tọrọ aforiji wipe ara oun ko ya. Ko pẹ lẹyin rẹ ni o pada sori ọrọ akọsọ naa. O ni o rẹ oun ni nitori wahala ipolongo ibo.

Tshisekedi gbajọba lọwọ Joseph Kabila fun igba akọkọ ni bi ọgọta ọdun ti wọn yoo gbe ijọba fun aarẹ miiran ni irọwọ-rọsẹ.