Day 22: Njẹ́ ẹni tí yóó borí ní ìdìbò 2019 ṣe pàtàkì bí?

Atiku, Buhari, Sowore, Moghalu ati Durotoye
Àkọlé àwòrán Ewo lo ṣee gbọkanle ninu awọn oludije?

Kini o ṣe pataki julọ lati ri ninu ẹni ti yoo jawe olubori nibi idibo Naijiria?

Ero ọpọlọpọ ni pe gbogbo ibo Naijiria, ko nii ṣe nipa ohun ti awọn oludije yoo ṣe fun ara ilu bikoṣe nipa erongba tara wọn nikan.

Nitori naa, njẹ idibo yi yoo tẹle ipasẹ ti atẹyinwa? Njẹ ẹni ti yoo wọle ṣe pataki si ara ilu tabi orukọ ẹgbẹ wọn tabi orukọ ẹbi wọn lo ṣe koko?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObasanjo: Atiku kìí se Áńgẹ́lì, àmọ́ yóò se dáadáa ní ìlọ́po méjì ju Buhari lọ

Ohun ti akọroyin BBC ba bọ ree.

Idibo de, gbogbo eniyan ni o si n ṣọrọ nipa rẹ ati awọn oludije to lokiki ju lọ.

Ni ọpọlọpọ ibi ipolongo ibo ni awọn eniyan ti maa n pariwo orukọ oludije. Ṣugbọn o jọ bi ẹni pe, idibo naa, orukọ ni yoo da le lori, ki i ṣe ipa ti awọn oludije le ko ninu iṣejọba.

Labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu mejeeji to tobi ju - APC ati PDP - ni Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji aarẹ nigba kan ri, Atiku Abubakar ti n dije.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin ló ni ilé àti àdúgbò fún ìdí èyí wọ́n lè ṣe ìlú dáadáa'

Oludije mejilelaadọrin ni o n dupo aarẹ bayi, ṣugbọn o jọ bi ẹni pe ohun ti awọn oludibo n wo nikan ni ẹni to ni irú ẹni ti oludije naa ba duro fun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionìpàdé ìtagbangba ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò gomina ní ìpínlẹ̀ Eko.

Arakunri Ernest Ereke to jẹ olukọ ni fasiti Abuja ni oun ro pe oriṣiriṣi nkan lo yẹ ni wiwo lati mọ irufẹ ẹni to yẹ ki awọn ara ilu yoo dibo fun.

Ṣugbọn njẹ awọn ara ilu bikita nipa ẹni ti yoo wọle ibo aarẹ?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsinbajo: Ikẹnnẹ yẹ kó jẹ́ Mẹ́kà òṣèlú ni

Akoroyin BBC beere ni awọn adugbo Abuja, pe kini iyatọ ti iru ẹni to ba wọle ibo naa yo mu wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMurphy Elégungun Rọba: Mo fẹ́ di ẹnití egungun rẹ rọ jùlọ ní àgbáyé

Oriṣiri ni ero ọmọ Naijiria, ṣugbọn iwadii ti fihan pe ọpọlọpọ lo ti gba kamu pé iwọnba ni ibo awọn nii fi ṣe pẹlu ẹni ti yoo wọle.

Itanjẹ atẹyin wa ninu ileri awọn oloṣelu ti jẹ ki awọn kan kunlẹ adura lati bẹ Ọlọrun ki awọn oludije le mu ileri wọn ṣẹ.

Awọn ti iṣejọba alagbada jẹ logun ti n poungbẹ pé asiko ti to lati mu awọn oludije mọlẹ ki wọn mu ileri wọn ṣe fara ilu to n to ninu ojo ati ninu oorun fi jade dibo fun won.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Ọpọ lo ti ni oye kikun pé nkan ti yipada si ti atẹyinwa ti awọn oloṣelu a kan maa tan oludibo jẹ lasiko idibo.

Bayii, imọran ti n wa pe ki ẹbi, ara, ọrẹ ati alabaṣiṣe fun oludije kọọkan maa ran wọn leti ileri wọn loorekoore.

Ati pe, oludije to ba kuna lati mu ileri rẹ ṣẹ ni saa akọkọ ko ni wọle lẹẹkeji nitori pe awọn oludibo ko ni dibo fun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFestus keyamo: Ọ̀rọ̀ Obasanjọ sí Buhari ti di ìrégbè