Ilé ńlá àràmàndà tó di ọgbà ẹ̀wọ́n

Caracas, Venezuela Image copyright ARCHIVO FOTOGRAFÍA URBANA / PROYECTO HELICOIDE
Àkọlé àwòrán Caracas, Venezuela

Ni aarin gbungbun olu ilu orilẹede Venezuela, Caracas ni ile aramanda yii wa.

Ile naa, El Helicoide ti figba kan jẹ ohun to n soju orilẹede naa gẹgẹ bi ilu ọlọrọ to si ni ọjọ iwaju rere.

Ṣugbọn lonii, o ti di ibi ti wọn nko awọn ti wọn ran lẹ ẹwọn si to si ti wa n sọ ti ijakulẹ orilẹede naa gẹgẹ bi ile ile nla to niyi ju ni ẹkun Latin America ati ibi ti idarudapọ ti wa n ṣẹlẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin ló ni ilé àti àdúgbò fún ìdí èyí wọ́n lè ṣe ìlú dáadáa'

Nkan bi ọdun 1950s ni wọn kọ El Helicoide laye igba naa ti orilẹede Venezuela ni ala ire to si n pa ọpọlọpọ owo wọle latara epo rọbi.

Ọgagun Marcos Perez Jimenez nigba naa lọhun fẹ ki iṣẹ akanṣe yii jẹ apẹrẹ orilẹede bi ẹṣin iwaju ti awọn tẹyin n wo sare.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Caracas, Venezuela

Venezuela jẹ orilẹede to jẹ wi pe lati ọdun 1948 lo ti wọ ijọba ologun, koko ọrọ aatẹle wọn si ni "a o tẹsiwaju bi a ba n kọ ile".

El Helicoide lo yẹ ko jẹ ile itaja to lokiki ju lagbaye plu ọṣọ rẹ to ga lọ soke roo ro to fi to iwọn iye ile itaja ọọdunrun eleyi ti wn la kalẹ pe yoo wa ninu ile naa.

O tobi gan to bẹẹ ti wọn lee foju rii ni ibi kibi ninu ilu Caracas.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWo fidio 'ẹwọn idẹra'

O yẹ ko ni ọkọ baalu tirẹ lọtọ, ile igbalejo si, akasọ onina ati oke tente ti yoo wa pataki jul fun ile naa.

Ṣugbọn lọdun 1958 ni gbogbo ala ire Marcos Perez pe ki iṣẹ akanṣe yii di ẹṣin iwaju ja sofo to si di ẹsin inu iwe lasan lasan.

Image copyright Archivo Fotografía Urbana / Proyecto Helicoide
Àkọlé àwòrán This space-age building was carved into the rock with ramps spiralling up past 300 planned boutiques

Ibi Ibẹru

Fun ọplọpọ ọdun, tandi ni ile naa duro soju kan ti ọpọlọpọ igbiyanju lati mu u pada bọ sipo si n ja si pabo.

Nigba 1980s, ijọba bẹrẹ si ni gbe awọn ajọ kan lọ si El Helicoide. Ṣugbọn lati igba naa, o ti di ile ibẹru eyi ti wọn n ko ati ọdaran atawọn oloṣelu ẹlẹwọn si

Ile iṣẹ BBC ti ba awọn to ti kuro lọgba ẹwọn yii, ẹbi wọn, awọn aṣoju onimọ ofin, ẹgbẹ ti ko rọgbọ ku le ijọba to fi mọ aṣọgba ẹwọn meji lati sọ itan gẹlẹ bi igba aye El Helicoide ṣe ri.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Caracas, Venezuela

Iṣoro ọrọ aje ati oṣelu

Igbe aye awọn eniyanm ni Venezuela bẹrẹ́ si ni le koko plu ifasẹyin ọrọ aje, aito ounjẹ ati oogun to fi mọ ọrọ iṣẹ oojọ ti gbogbo ti fẹ di akurẹtẹ.

Ikọlukọgba wa pọ ni El Helicoide gẹgẹ bi ọkọ to kun fun awọn ẹlẹwọn ṣe n wọ ọgba ẹwọn lojoojumọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Caracas, Venezuela

'Ifoya de fun gbogbo araalu'

Oṣiṣẹ ọgba ẹwọn tẹlẹ ri ti ko fẹ fi oju ara rẹ han sọ fun BBC pe idi ti wọn fi n ṣe eyi ni lati dẹru ba awọn eniyan ni.

"Mo dẹ ro wi pe wọn ṣe bẹ́ẹ́. Nitori kete ti iwọde tabi ifẹhonu kan han ba bẹ́ si igboro, ọpọlọ araalu lo maa n bẹru ki ọlọpaa ma mu wọn.

Ojoojumọ, ọsọọsẹ koda, oṣooṣu lawọn ẹlẹwọn ni El Helicoide ma n foju ba ile ẹjọ.

Gbogbo igba lo maa n la ala ifiyajẹni to n waye lojojumọ ni ọgba ẹwọn naa.

Àkọlé àwòrán Caracas, Venezuela

Bi lẹwọn ṣe n pọ sii ni El Helicoide ni awọn aṣọgba n wa ọna ati tun wa aaye sii.

Ọfiisi, ile igbọnsẹ, atawọn akaba to yẹ ko da wa fun ile iṣẹ naa ni wọn ti pa ti wọn sọ di ọgba ẹwọn.

Ko si ina, ko si omi, ko si ile igbọns bẹẹ ni ko si imọtoto kankan. Ṣe ni gbogbo ogiri kun fun idọti ẹjẹ ati igbẹ.

Ẹlẹwọn le ma wẹ fun odidi ọsẹ kan. Inu ike rọba ni wọn n tọ si, inu ọra ni wọn si n ṣe igbọnsẹ si.

Àkọlé àwòrán Caracas, Venezuela

Ifiyajẹni

Mo ti gbọ awọn ti wọn fi awọn nkan to lewu ba lo pọ pẹlu ipa.

Mo ri awọn ti wọn so lokun mọ oke ti wọn si da ori wọn kodo ko maa mi jolojolo. Wọn a maa ki batiiri bọ ina lati fi maa gun wọn lara.

Bi wọn ṣe n tẹ ẹtọ awọn eniyan loju mọlẹ yii lagbara. Tori naa, awọn ile iṣẹ to n ja fun ẹtọ ọmọniyan ti ni akọsilẹ gbogbo eyi loṣu keji ọdun 2018 ti wọn si n gbe igbesẹ pẹlu ifọwọsowọpọ ijọba orilẹede Venezuela.

Àkọlé àwòrán Caracas, Venezuela

Ninu oṣu karun un ọdun 2018, awọn ẹlẹwọn El Helicoide fi ẹhonu han lori ohun ti wọn n la kọja. Lẹyin ọpọlọpọ iṣẹlẹ to ti waye, wọn da awọn ẹlẹwọn kan silẹ pẹlu ileri lati mu ayipada ba aye wọn.

Ṣugbọn pẹlu alaye awọn to wa ninu ọgba ẹwọn, ko fibẹẹ tii si ohun ti wọn ṣe gẹgẹ bi atunṣe si El Helicoide.

pẹlu gbogbo akitiyan lati kan si ile iṣẹ to n ri si ibanisọrọ ni Caracas ati aṣoju ijọba Venezuela nilẹ United Kingdom, BBC ko tii ri esi kankan si awọn ibeere yii.