Tanko Mohammed: Agbẹjọ́rò 250 ni Adájọ́ Àgbà ṣe ìbúra fún

CJN tuntun Image copyright Aliyu Tukur
Àkọlé àwòrán Adájọ́ Àgbà tí Ààrẹ Buhari sẹ̀sẹ̀ yàn,Tanko Mohammed ti se ìbúra wọlé fún àwọn agbẹjọ́rọ̀ tó ń gbọ́ ẹjọ́ ètò ìdìbò.

Ọgọọrọ awọn agbẹjọrọ lo pejọ pọ si ibi ibura wọle fun awọn agbẹjọrọ ti yoo ma gbọ ẹjọ to nii se pẹlu eto idibo.

Adajọ Agba tuntun lorilẹede Naijiria, Ibrahim Tanko ti Aarẹ Buhari sẹsẹ yan lo ṣe ibura wọle fun ajọ to n gbọ ẹjọ eto idibo naa.

Ile ẹjọ to gaju lorilẹede Naijiria ni wọn ti ṣe iburawọle fun awọn alaga ati awọn ọmọ ẹgbẹ ajọ ti yoo ma gbọ ẹjọ to nii se pẹlu eto idibo naa.

Image copyright Aliyu Tukur

Laipe yii, Aarẹ Muhammadu Buhari yọ Adajọ Agba, Walter Onnoghen kuro nipo fun igba diẹ, titi ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ iwa ibajẹ yoo fi abajade ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi kan an.