Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà fèsì sí ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì,EU àti Amẹ́ríkà

Ààrẹ Buhari Image copyright Getty Images

Ijọba orileede Naijiria ti fẹsi si orileede Amerika, ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu ati ilẹ Gẹẹsi lori ọrọ adajọ agba Walter Onnoghen ti wọn ni aṣẹ lọ rọọkun nile rẹ ko boju mu.

Esi yi jẹ idahun si atẹjade kan ti awọn orileede mejeeji fi sita lọjọ ẹti nibi ti wọn ti ni ko tọ bi ẹka alaṣẹ ijọba Naijiria ti ṣe yọ adajọ agba naa ni ogunjọ si idibo apapọ

Ninu atejade kan ti agbẹnusọ ijọba Garba Shehu fi sita ti a ri ka loju opo ile iṣẹ iroyin Naijiria NAN, ijọba ni ''awọn lodi si ayọnusọ kankan to n gbero lati da ifoya silẹ́ laarin ara ilu tabi to fẹ ṣe idiwọ fun eto idibo to n bọ lọna.''

Garba Sheu tẹsiwaju pe ijọba Naijiria lẹtọ lati gba tabi kọ amọran lori akoso ilu ti o si tọ ki awọn orileede agbaye to ku naa bọwọ fun ẹtọ yi.

O ni ijọba ko lodi si ibaṣepo ti yoo mu ki eto idibo to n bọ lọna kẹsẹjari.

Awuyewuye ọrọ aṣẹ lọ́rọkunle ti ijọba Naijiria pa fun afdajọ agba Walter Onnoghen ati bi wọn ti ṣe yan adajọ miran dipo rẹ jẹ ọrọ to gbode ni Naijiria toun ti bi idibo ọdun 2019 ti ṣe n sunmọ le.

Yatọ si iriwisi lọdọ awọn amofin,ẹgbẹ alatako, Ile Asofin agba Naijiria ti ni awọn yoo ṣe ijoko pajawiri kan lati mẹnu ba ọrọ yi lọjọ iṣẹgun.