Báyìí ni àwọn olùdíje ìpínlẹ̀ Eko ṣe fẹ́ kojú ìṣòro ìlera

àwọn olùdíje ìpínlẹ̀ Eko Image copyright Babatunde Olalere Gbadamosi/Facebook
Àkọlé àwòrán àwọn olùdíje ìpínlẹ̀ Eko

Ọpọlọpọ ni ipenija to maa n koju ilu kan, bẹẹ naa ni ipinlẹ Eko n koju tirẹ.

Nibi ipade ifọrọwerọ awọn oludije gomina ni ipinlẹ Eko eyi ti BBC Yoruba ṣe agbekalẹ rẹ, awọn oludije ṣalaye lọlọkan o jọkan.

Nipa eto ilera ni ipinlẹ Eko, gbogbo awọn oludije lo ṣalaye ilana eto ti wọn ni fun ilera.

Babatunde Gbadamọsi (ADP)

Àkọlé àwòrán àwọn olùdíje ìpínlẹ̀ Eko

Gbadamọsi tẹnu mọ eto ilera ọfẹ fun tolori tẹlẹmu ni ipinlẹ Eko. O ni ẹni to lowo lo n san owo eto adojutofo ṣugbọn ni ijọba toun, ilera ọfẹ ni.

Bakan naa, ni ti ọmọde ati arugbo, Babatunde ni wọn a fi wọn ṣe akọkọ bi wọn ba n boju to awọn alaisan ti wọn ba jọ wa lori ila.

O ni iṣejọba oun yoo kọ ibudo ilera ti ijọba si awọn apa ibi ti ko tii si ile iwosan ni ipinlẹ Eko bẹẹ si ni wọn yoo kọ ile iwosan si awọn ijọba ibilẹ ti ko tii ni ile iwosan.

Ọmọlara Adesanya (YPP)

Àkọlé àwòrán àwọn olùdíje ìpínlẹ̀ Eko

Arabinrin Ọmọlara Adesanya gbagbọ pe kii ṣe keeyan kan ni ibudo ilera tabi ile iwosan ti ijọba nikan ṣugbọn pipese oogun ṣe pataki.

Gbogbo nkan ti yoo jẹ ki awọn ibudo ilera kekeke ni fun iṣẹ ni ijọba rẹ yoo pese. Wọn yoo kọ awọn nọọsi niṣẹ wọn yeke yeke.

Bẹẹ si ni yoo rii daju pe bi o tilẹ ṣe ẹyọkan ti wọn yoo si maa sanwo fun, dokita yoo maa wa lawọn ibudo ilera alabọde.

Awọn ẹrọ amuna wa naa yoo wa dipo awọn daku daji tokunbọ tabi aloku to n da ẹmi awọn eeyan legbodo bii ni akoko ti wọn ba n ṣe iṣẹ abẹ

Muyiwa Fafowora (ADC)

Àkọlé àwòrán àwọn olùdíje ìpínlẹ̀ Eko

Fafowora gbagbọ pe ilu Eko lowo gan o si gbagbọ pe ọ̀pọ ninu isuna ipinlẹ lo yẹ ki wọn na sori eto ilera.

Eto ilera adojutofo ni Fafowora yan lati ṣe leyi ti awọn eniyan yoo maa da owo kọbọ kọbọ bii irinwo naira si ibi ti wọn yoo ti maa mu u lo nigba ti ailera ba de.

Awọn to si jẹ arugbo ti ko lagbara ati san owo mọda mọda yii ni wọn yoo ṣe e fun lọfẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸ wo ọ̀nà àbáyọ tí àwọn olùdíje gómìnà pèsè sí ìṣòro Eko

Ọmọọbabinrin Adebisi Ogunsanya (YPP)

Àkọlé àwòrán àwọn olùdíje ìpínlẹ̀ Eko

Adebisi Ogunsanyan ni ijọba oun yoo yẹ owo ti awọn eleto ilera n gba ni owo oṣu wo wọn yoo si fi kun un nitori ọpọlọpọ wọn ni ko gba owo ti ko peye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin ló ni ilé àti àdúgbò fún ìdí èyí wọ́n lè ṣe ìlú dáadáa'

Bakan naa o mẹnu ba pipese oogun, awọn ẹrọ igbalode to tọ si awọn ile iwosan to yẹ. Bakan naa wọn a ri i pe wọn mo ju to ago ti awọn ile iwosan mii ma n tilẹkun ki awọn eniyan le maa ba wọn bi wọn ba gbe alaisan lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionìpàdé ìtagbangba ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò gomina ní ìpínlẹ̀ Eko.