Ìgbìmọ̀ iṣedajọ orílè-èdè Nàìjíríà NJC fẹ́ ṣèpàdé lórí Onnoghen

Aworan awọn ọmọ igbimọ iṣedajọ orílè-èdè Nàìjíríà NJC Image copyright NJC
Àkọlé àwòrán Ìgbìmọ̀ iṣedajọ orílè-èdè Nàìjíríà NJC lagbara lati jiroro nipa yiyọ adajọ kankan lorileede Naijiria

Igbimọ iṣedajọ orile-ede Naijiria n palẹmọ lati ṣe ipade pajawiri lori ọrọ adajọ agba Naijiria Walet Onnoghen ti ijọba apapọ fun ni iwe lọọrọkun nile.

Ohun ti a gbọ ni pe ipade naa yoo waye lọjọ Aje ni deede agogo mẹwaa owurọ.

Iwe Iroyin Cable ni ọkan lara awọn ọmọ igbimọ naa ti wọn tu kẹkẹ ọrọ yi ni awọn ko ni jẹ ki adajọ agba Onnoghen tabi adele rẹ ti ijọba ṣẹṣẹ yan kopa ninu ipade naa.

Image copyright @CREVO360_NG
Àkọlé àwòrán Adajọ agba Naijiria, Walter Onnoghen

Igbimọ iṣedajọ yi labẹ ofin ni Naijiria lo lagbara lati jiroro tabi paṣẹ, lẹyin agbeyẹwọ ẹri, yiyọ adajọ kankan kuro nipo titi to fi de ori adajọ agba orile-ede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸ wo ọ̀nà àbáyọ tí àwọn olùdíje gómìnà pèsè sí ìṣòro Eko

Ipade to yẹ ki igbimọ naa ṣe laipe yi ko waye nitori pe adajọ agba Walter Onnoghen sun un siwaju.

Lọwọlọwọ, ọrọ yiyọ adajọ Onnoghen nipo ti n da awuyewuye silẹ laarin awọn amofin ati ẹka alaṣẹ ijọba ti a si gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ agbẹjọro ati awọn ẹgbẹ ajafẹtọ ẹni kanna fẹ ṣe ipade pajawiri ati iwọde.

Lọjọ Iṣẹgun ni ile igbimọ aṣofin agba Naijiria naa fi ọjọ ipade pajawiri si lati jiroro lori ọrọ yi kan naa.

Ninu ọrọ tirẹ agbẹnusọ fun Aarẹ Buhari, Garba Sheu sọ lalẹ ọjọ Aiku pe nitori ti Aarẹ Buhari ko fi ẹlẹ yọ Onnoghen lawọn eeyan Naijiria ti ṣe n binu.

O salaye pe aṣẹ ile ẹjọ ni Aarẹ tele lati yọ Onnoghen nipo ti ko si ni nkankan ṣe pẹlu lilo agbara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsinbajo: Ikẹnnẹ yẹ kó jẹ́ Mẹ́kà òṣèlú ni
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin ló ni ilé àti àdúgbò fún ìdí èyí wọ́n lè ṣe ìlú dáadáa'