Sharafadeen All ni olùdíje sí ipò gómìnà ZLP ní ìpínlẹ̀ Ọyọ

Lọwọlọwọ, oun ni Asaju Balogun Olubadan ilẹ Ibadan. Image copyright Sharafadeen Alli/facebook
Àkọlé àwòrán Lọwọlọwọ, oun ni Asaju Balogun Olubadan ilẹ Ibadan.

Wọn bi Sharafadeen Abiodun Alli ni ọdun 1963, ni ilu Ibadan.

O kẹkọ gboye nipa imọ ofin ni Fasiti ilu Ibadan lọdun 1986. O bẹrẹ iṣẹ amofin ni ileesẹ ofin R.A Sarumi & Co ni ilu Ibadan laarin ọdun 1988 si 1991.

Lẹni ọdun mejidinlọgbọn, o di Alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan lọdun 1991.

Wọn fi jẹ oye Asiwaju Balogun ilu Bakatari ni ijọba ibilẹ Ido, lọdun 1992 lẹni ọdun mọkandinlọgbọn.

Wọn dibo yan an ni aṣoju ẹkun idibo Guusu Ọyọ labẹ ẹgbẹ osẹlu UNCP lọdun 1996, ṣugbọn wọn ko bura fun nitori igbesẹ awọn ọmọ ologun to waye.

Image copyright Sharafadeen Alli/facebook

Ṣaaju asiko yii, o jẹ ọmọ igbimọ ẹlẹni mẹjọ to wa fun idasilẹ Ibadan City Development Corporation labẹ iṣakoso Gomina Kọlapọ Iṣhọla lọdun 1992.

O di Akọwe ẹka ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party(PDP) nipinlẹ Ọyọ lọdun 1999. Bakan naa lo jẹ Adele Alaga ẹgbẹ naa ninu Oṣu Kẹsan, ọdun 1999.

Wọn yan an sipo Akọwe ijọba ipinlẹ ọyọ labẹ iṣakoso Gomina Rashidi Ladọja lọdun 2003.

O jẹ oye Akọgun ilẹ Ibadan lọdun 2004.

Lọdun 2005, o jẹ Olori oṣiṣẹ fun Gomina Rashidi Ladọja.

Wọn yan an sipo gẹgẹ bi Alaga ileeṣẹ Odu'a Investment Company Limited lọdun 2011.

Lọwọlọwọ, oun ni Asaju Balogun Olubadan ilẹ Ibadan.

Lọdun 2015, o dije dupo igbakeji gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour ni ipinlẹ Ọyọ.

Nibayii, oun ni oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ labẹ ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party fun eto idibo ọdun 2019.