Onnoghen: Ọlọ́pàá ti ọ́fíísì adajọ́ àgbà, wọn tún lé àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ jáde

Onnghen ati awọn ọlọpaa to gbe ibọn dani

Igbimọ to n gbọ̀ ẹsun ti wọn ba fi kan awọn to di ipo mu nilu, CCT ti dun igbẹjọ Adajọ agba nigba kan fun Naijiria, Walter Onnoghen siwaju.

Lasiko igbẹjọ to yẹ ko waye lọjọ Aje lori ẹsun ṣiṣe mago-mago dukia ti wọn fi kan Onnoghen ni Alaga igbimọ naa, Danladi Usman kede pe wọn ko ti i le sọ ọjọ ti igbẹjọ naa yoo tun tẹsiwaju nitori pe wọn n duro de idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun ti Onnoghen ti pe ẹjọ tako igbesẹ igbimọ naa.

Ṣaaju ni iroyin tẹ BBC Yoruba lọwọ pe ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria ti ofiisi Adajọ Agba Walter Onnoghen pa, ti wọ́n si tun le awọn oṣiṣẹ́ to n ṣiṣẹ pẹlu rẹ jade.

Aarọ kutu ọjọ Aje ni a gbọ pe awọn ọlọpaa ya bo ofiisi adajọ agba naa, lẹyin ọjọ mẹta ti Aarẹ Muhammadu Buhari ni ko lo fidi mọ 'le.

Iroyin ni igbesẹ naa waye lati ri pe Onnoghen ko ri aye wọ ofiisi naa nigbakugba.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Frank Mba ko ti i sọrọ lori igbeṣẹ yii, ṣugbọn agbẹnusọ fun Onnghen, Awusam Bassey ni ootọ ni pe wọn ti ti ofiisi naa pa.

Awọn oniroyin ti ọrọ ṣe oju wọn ni, ṣe ni awọn ọlọpaa de ofiisi naa ti wọn si sọ fun awọn oṣiṣẹ to wa ninu awọn ofiisi to yii ka ki wọn fi ijoko wọn silẹ lẹyin ti wọn si tii pa.

Iwọ́de ń wáyé ní Abuja, Eko ati Enugu

Iroyin to n tẹ BBC Yoruba lọ́wọ́ fi han wipe iwọde n lọ lọwọ ni Abuja, Ilu Eko ati Enugu lati fi ẹhonu han lori bi Buhari ṣe yọ Onnoghen.

Ni Abuja, awọn ọmọ ẹgbẹ amofin kan ti bẹrẹ si ni ṣe iwọde ni oriko ẹgbẹ awọn amofin Naijiria (NBA) ni Abuja bayii.

Akọ̀royin BBC ni, kò pẹ́ tí iwọde naa bẹrẹ ti awọn kan de ninu ọ̀kọ̀ nla mérin ti wón si da aarìn wón ru. Wọn ni awọn n ṣe atilẹyin fun igbesẹ̀ ijọba ni.

Àkọlé àwòrán Ifẹhonu han n lọ lọwọ ni oriko NBA nipa ọrọ Onnoghen

Ẹ o ranti wipe ni ọjọ Ẹti, amofin agba Olisa Agbakoba to bẹnu atẹ lu igbesẹ Buhari lati yọ Onnoghen ti ni awọn yoo ṣe iwọde lati fi ẹhonu han lori igbesẹ aarẹ naa.

Agbakoba tun fa ijọba apapọ lọ ile ẹjọ lori ọrọ naa.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí: