Ile Asofin Eko: Ọjọ́ Kẹrin oṣù Kejì ni Ambọde yóò yọjú síwájú ilé

Ambode Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ọjọ Aje ni iroyin gba ilẹ kan pe ile asofin ni ipinlẹ Eko ti n gbe igbesẹ lati yọ gomina Ambode kuro ni ipo.

Ile igbimọ Asofin ni ipinlẹ Eko ti fi iwe pe gomina ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambode lati wa jẹjọ ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi kan an, ko lee ni anfaani lati wa sọ tẹnu rẹ.

Ile igbimọ Asofin gbe igbesẹ yii pẹlu awijare pe gomina Ambọde n na owo ti ile asofin ko fọwọsi.

O si ti to ọjọ mẹta bayii ti ẹnu ti n kun gomina Ambode pe, oun lo n dọgbọn se agbatẹru eto ipolongo oludije gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP, Jimi Agbaje, to si n gbe owo kalẹ fun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nibi ijoko ile asofin to waye lojọ Aje, ni wọn ti ka awọn ẹsun sise owo ilu basubasu si gomina Ambọde lọrun, ti wọn si ransẹ pe ko wa sọ tẹnu rẹ.

Ile ti wa pasẹ fun gomina Ambọde pe ko yọju sibi ijoko ile ti yoo waye lọjọ kẹrin osu keji ọdun yii lati wa wi awuijare rẹ.

Wọn ti wa sun ijoko ile di Ọjọ Kẹrin,Osu Keji, ọdun to n bọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn olùgbọ́ BBC Yoruba fi èrò han lẹ́yìn #BBCGovDebate Eko

Nibi ijoko ile to waye ni iroyin ti tan kalẹ pe wọn n gbimọ lati yọ gomina naa kuro ni ipo.

Lọwọlọwọ bayii, ijoko ile asofin si n tẹsiwaju, a o ma a mu iroyin wa fun yin lẹkunrẹrẹ.