NBA: Á kọ́ ilé aṣòfin àpapọ̀ nípa agbára tó ní lórí Ààrẹ tó bá tẹ òfin lójú

Awọn irinṣẹ igbẹjọ Image copyright @Nigerialawyers
Àkọlé àwòrán Àwọn amòfin náà ní gbogbo ọ̀nà tí òfin là kalẹ̀ làwọn yóò tọ̀

Awọn amofin kaakiri ẹkun iwọ oorun guusu orilẹede Naijiria, darapọ mọ awọn agbẹjọro kaakiri orilẹede Naijiria, lati bẹrẹ igbesẹ idẹyẹsi ile ẹjọ.

Wọn n gbe igbesẹ yii lati fi ẹhonu han si bi aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ni ki adajọ agba orilẹede Naijiria, Water Onoghen yẹ̀bá si ẹgbẹ kan naa lori ẹsun aijolootọ ninu iwe akojọpọ dukia rẹ.

Awọn amofin lorilẹede Naijiria labẹ agboorun NBA ni ohun ti aarẹ ṣe tako agbekalẹ iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn olùgbọ́ BBC Yoruba fi èrò han lẹ́yìn #BBCGovDebate Eko

Ni ọjọ iṣẹgun ti igbesẹ naa bẹrẹ si ni fi idi mulẹ, awọn amofin kaakiri awọn ipinlẹ bii Ondo, Ọṣun, Ọyọ , Ogun ati Ekiti naa darapọ.

Alaga ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni ilu Akurẹ, Amofin Ọla Dan Ọlawale ni gbogbo awọn amofin ipinlẹ naa ni wọn tẹle aṣẹ ti olu ileeṣẹ ẹgbẹ naa pa.

O ni gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ amofin NBA, ko si amofin kankan to tẹ awọn ile ẹjọ ni ipinlẹ naa.

Image copyright @Nigerialawyers
Àkọlé àwòrán Àwọn amòfin náà ní ẹ̀ka ìṣèdájọ́ yóò padà sí ẹsẹ̀ ògo rẹ̀.

O ni lootọ ọrọ naa yoo kan awọn eeyan to ni ẹjs niwaju ile ẹjọ kan tabi omiran lọjọ mejeeji ti igbesẹ naa yoo fi waye, sibẹ 'Ki ọrọ maa baa bajẹ' lawọn amofin fi gbe igbesẹ naa.

Ni tirẹ alaga ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni agbegbe Ileṣa nipinlẹ Ọṣun, Amofin Kanmi Ajibọla ṣalaye pe gẹgẹbii ara smọ igbimọ ẹgbẹ amofin NBA to joko lori ọrọ naa, iroyin lati gbogbo tibu-toro orilẹede Naijiria fihan pe aṣẹ naa fidi mulẹ kaakiri gbogbo ẹkun igbẹjọ lorilẹede Naijiria.

Image copyright @Nigerialawyers
Àkọlé àwòrán Awọn alaga ẹgbẹ amofin ni Akurẹ ati Ilesa ni awọn agbẹjọro n tẹle aṣẹ naa

O ni awọn amofin ṣetan lati gbe igbesẹ gbogbo to tọ lati rii pe wọn pe Aarẹ Buhari pada lori igbesẹ naa.

"Lara awọn igbesẹ ti a o gbe lẹyin ti gbedeke ọjọ meji naa ba pari ni lati wo boya ki a tẹ siwaju tabi ki a gba ile aṣofin apapọ lọ, lati da wọn lẹkọ lori awọn ọna ati agbara ti ofin fun wọn lati da sẹria to ba yẹ fun Aarẹ to ba ya aletilapa lori ọrọ ibọwọ fun ofin."