New Minimum Wage: Ilé ìgbìmọ̀ aṣojú ṣòfin bọwọ́ lu #30,000 fáwọn òṣìsẹ́

Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ Image copyright Twitter/NLC
Àkọlé àwòrán Owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ

Ile igbimọ aṣoju ṣofin l'Abuja ti buwọ lu aba lati maa san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.

Igbesẹ naa waye lẹyin ti igbimọ to n ri si alekun owo oṣu oṣiṣẹ tuntun jabọ fun ile.

Gbogbo ile lo fọwọ si pe ki ijọba bẹrẹ si san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira gẹgẹ bi owo oṣu tuntun fun oṣiṣẹ to kere julọ fawọn oṣiṣẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFalana: Awọn to n dije dupo ìdìbò 2019 fẹ́ fa ogun si Naijiria

Eleyi wa ni ibamu pẹlu aba ti igbimọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari gbe kalẹ lati ṣiṣẹ lori alekun owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ da.

Aarẹ Buhari ti kọkọ fọwọ si ẹgbẹ mẹtadinlọgbọn naira tẹlẹ ṣugbọn awọn oṣiṣẹ kọ jalẹ pe ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira lawọn yoo gba gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.