Onnoghen: Àjọ NJC fún Onnoghen lọ́jọ́ méje láti wá sọ tẹnu rẹ̀

Adajọ Ibrahim Tanko Mohammed ati Walter Onnoghen Image copyright Nigeria Bar Association
Àkọlé àwòrán Ajọ NJC pe awọn adajọ agba mejeeji

Ajọ to n ri si idajọ lorilẹede Naijiria NJC ti fun adajọ agba Walter Onnoghen ti Aarẹ Muhammadu Buhari ni ko lọ rọku nile ati adajọ agba tuntun to gba ipo rẹ Ibrahim Tanko Mohammed lọjọ meje lati fesi si awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Ajọ NJC ni ki adajọ agba Onnoghen fesi si ẹsun ti wọn kan an pe o kuna lati kede dukia rẹ gẹgẹ bi ofin Naijiria ti fi lelẹ.

Bakan naa, ajọ NJC ni ki adajọ agba tuntun Mohammed ti Aarẹ Buhari ṣẹṣẹ bura fun wa sọ tẹnu rẹ idi ti o fi gba iyansipo naa lai jẹ pe ajọ NJC fọwọ si.

Ti o ba ṣẹlẹ pe awọn adajọ agba mejeeji jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ti wọn si da wọn duro, adajọ Ọlabọde Rhodes-Vivour to jẹ adajọ kẹta to ni iriri julọ ni ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ni yoo gori aleefa gẹgẹ bi adajọ agbajọ tuntun.

Atiku fẹjọ́ Buhari sun US, UK, France àti EU lórí ọ̀rọ̀ Onnoghen

Ẹwẹ, oludije aarẹ fẹgbẹ oṣelu alatako PDP, Atiku Abubakar ti fẹjọ aarẹ Muhammadu Buhari sun orilẹede Faranse, Germany, Amẹrika, Ilẹ Gẹẹsi ati ajọ ilẹ alawọ funfun lori bi o ti ni ki adajọ agba Walter Onnoghen lọ rọkun nle.

Image copyright Twitter/PDP
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori adajọ agba tẹlẹ Walter Onnoghen

Bakan naa ni Atiku tun fẹsun kan Aarẹ Buhari ninu ẹjọ to fi sun pe o n gbe igbesẹ ti ko ba ijọba awa arawa mu.

Atiku ni Aarẹ Buhari n tapa ṣofin orilẹede Naijiria, bẹẹ lo si n o ṣe awọn ẹka ijọba bi o ṣe wu u lati le tẹ ara rẹ nikan lọrun.

Oludije fun ipo aarẹ ẹgbẹ PDP sọ pe lẹyin ọrọ adajọ agba ti Buhari yọ bii jiga, o ni bakan ni o ti bọwọ lu biliọnu dọla kan fun inanwo ile isẹ ologun ko to gbe aba rẹ de iwaju ile aṣofin agba l'Abuja.

Atiku tun fikun ọrọ rẹ pe, Buhari ko bọwọ fun aṣẹ ile ẹjọ lorilẹede Naijiria, bẹẹ lo tun fẹsun kan-an lori rira ọkọ ofurufu Tucano.