Ọlọ́pàá Ondo: Ìyá ọmọ tó kú yóò fojú balé ẹjọ́

Iya to n lu ọmọ rẹ Image copyright @Sazisokhango

Ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ti fi idi rẹ mulẹ wi pe, lootọ ni iya kan lu ọmọ rẹ pa ni Akure, ni ipinlẹ Ondo.

Ọmọ naa to papoda, ti orukọ rẹ n jẹ Mattew, wa ni ile -iwe girama onipele ikẹta.

Agbẹnusọ fun ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Femi Joseph to fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba sọ wi pe iwadii n lọ lọwọ lori isẹlẹ to waye ni agbeegbe Ọda, Akure ni ipinlẹ Ondo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo: Iya lu ọmọ pa nítori ẹgbẹ̀rún mọkànlélógun Naira

Awọn ti ọrọ naa soju rẹ wi pe Abilekọ Ajọkẹ Adebayo lo fi lulu ba ti ọmọ rẹ jẹ, lẹyin to ni ọmọ ọdun mẹrinla naa ji ẹgbẹ̀rún mọkànlélógun Naira(21,000) kuro ninu apo isuna rẹ ni ile ifowopamọsi.

Wọn fikun wi pe lẹyin ti iya naa ri wi pe ọmọ oun ji owo naa, o pe ọkọ rẹ to jẹ ọlọpaa lati fi ẹjọ ọmọ naa sun, ti baba ọmọ naa si pasẹ wi pe ki wọn na ọmọ naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìyá ọmọ tí ó kú yóò fojú balé ẹjọ́

Iya ọmọ ati aburo ọkọ na ọmọ naa, wọn si tii mọ inu ile. Ọrẹ ọmọ naa lo wa wọ ọmọ naa ,ti wọn si ri wi pe o ti daku, ko to di wi pe o gbe ẹmi mi ni ile iwosan.

Awọn ọlọpaa ti fi panpẹ ọba mu iya ọmọ naa, ti wọn si n wa baba ọmọ naa.