UK: Fiona Onasanya parọ́ pé òun kọ́ ló wa ọkọ̀ sáré àsájù

Fiona Onasanya Image copyright PA
Àkọlé àwòrán Fiona Onasanya nigba to de ile ẹjọ Old Bailey

Aṣòfin kan to tun jẹ oloṣelu akọkọ ti yoo di ero ẹwọn fun oṣù mẹ́ta , Fiona Onasanya, lo jẹbi ẹsun pe o purọ fun awọn ọlọpaa nigba ti wọn jawe fun wipe o n fi ọkọ rẹ sare ju.

Fiona Onasanya to jẹ amofin ni, ki i ṣe oun lo n wa ọko ti awọn ọlọpaa ri to sare ju gbedeke 30mph, ti ofin gba laaye ni popona kan ni orilẹede naa ni oṣu keje ọdun 2017 in July 2017.

Aṣofin naa, to n ṣoju Peterborough ni ẹgbẹ oṣelu rẹ jawe gbele-ẹ fun, lẹyin ti wọn ni o tẹ oju ofin mọlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹwọn oṣu mẹta ni wọn fun un lẹyin ti wọn tun igbẹjọ rẹ ṣe ni ile ẹjọ Old Bailey.

Inu ọkọ Nissan Micra yii ni wọn ti ni Onasanya sara asapajude naa.

Image copyright Jonathan Brady/PA
Àkọlé àwòrán Fiona Onasanya de si ile ẹjọ Old Bailey fun igbẹjọ rẹ ni ọjọ Iṣẹgun

Ile ẹjọ naa gbọ wipe, Onasanya n fi ẹrọ ilewọ rẹ tẹ atẹjiṣẹ nigba ti o n wa ọkọ rẹ ti o si n sare.

Oun ni aṣofin ti wọn yoo kọkọ sọ sẹwọn lẹyin ti Terry Fields lọ ẹwọn ọgọta ọdun, nitori wipe ko san owo ori £373 ni ọdun 1991.

Aburo Onasanya, Festus naa lọ ẹwọn oṣu mẹwa fun ipa to ko niinu ọrọ naa.

Image copyright PA
Àkọlé àwòrán Festus to jẹ aburo ọnasanya lọ ẹwọn oṣu mẹwaa

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionA ò ṣe àyọnusọ lóri ọ̀rọ̀ abẹ́lé Nàìjíríà-UK