Day 17: Àwọn olórí tó wà ní Kwara ń ṣe fún ara wọn nìkan ni #BBCNigeria2019
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nigeria 2019 Elections: Ẹgbẹ́ wa jẹ́ ẹgbẹ́ tó lójú àánú - Issa Aremu, Kwara Labour Party

Olùdíje gómìnà fún ẹgbẹ́ òṣèlú Labour ní ìpínlẹ̀ Kwara, Issa Aremu bu ẹnu àtẹ́ lu bí ìjọba tó wà lórí àléfà lọ́wọ́ lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Kwara ṣe ń ṣe ìjọba.

Issa ṣàlàyé pé tẹ́lẹ̀, Kwara lọ sókè torí àwọn olórí tó ń sin ara ìlú ṣùgbọ́n ó ní lónìí, àwọn olórí tó wà ní Kwara ń ṣe fún ara wọn nìkan ni.

Issa Aremu fi kún un wí pé ọ̀rọ̀ owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ kìí ṣe ojú àánú, bí kò ṣe pé wọ́n ṣiṣẹ́ fún un ni. Ó sì ní ẹgbẹ́ àwọn yóò san gbogbo owó tí wọ́n ń jẹ òṣìṣẹ́ ní Kwara.