America: Ẹ má dúró ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá lọ níta ìlú yóò tutù kọjá àlà

America yóò tutù ju bó ti yẹ lọ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán America yóò tutù ju bó ti yẹ lọ

Lọsẹ yii, awọn alasọtẹlẹ oju ọjọ ti ni awọn ara ilẹ Amẹrika yoo gbọn pẹpẹpẹ ninu otutu to lagbara ju bo ti yẹ lọ.

Awọn onimọ nipa oju ọjọ sọ pe o jẹ iṣẹlẹ to maa n sẹlẹ lẹẹkan laarin iran kan.

Wọn ni o maa n waye nigba ti oju ọrun ba ran afẹfẹ to tutu gan si ile aye to si fa ọpọlọpọ iṣlẹ to mu otutu dani. Pẹlu eyi, yoo mu iwọn oju ọjọ walẹ si 53C (-64F).

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDay 17: Àwọn olórí tó wà ní Kwara ń ṣe fún ara wọn nìkan ni #BBCNigeria2019

Ẹwẹ awọn onimọ nipa oju ọjọ ni ipinlẹ Iowa ti kilọ fun awọn ara ilu naa pe ki wọn ṣọra fun mimi kanlẹ ki wọn si din ọrọ sisọ ku bi wọn ba wa ni ita.

o kere tan eniyan miliọnu marun le laadọta ni yoo fara gba ninu iṣẹlẹ otutu to le yii.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán America yóò tutù ju bó ti yẹ lọ

Koda wọn ti kede konile o gbele lawọn apa ibi kọkan ni il naa.

Awọn onimọ nipa oju ọjọ sọ pe ohun ti yoo fa ijamba ni ki eniyan duro si ita ninu otutu to lagbara naa fun iṣẹju mẹwaa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán America yóò tutù ju bó ti yẹ lọ

Laarin ọjọ iṣgun si ọjọbọ si ni ni awọn alasọtẹlẹ oju ọjọ ni yoo waye ti wọn si ni pe Chicago yoo tutu ju ẹkun Antarctica.

Bẹẹ si ni ni awọn apa ibomiiran, yinyin ti wọn yoo foju ri yoo le gan.