Libya Refugees: Àtìpó 162 míì dé padà láti Libya

Awọn Naijiria nilẹ Libya Image copyright NEMA
Àkọlé àwòrán Awọn Naijiria nilẹ Libya

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, NEMA ti gba awọn ọmọ Naijiria mẹrindinlaadọrin to jẹ atipo ni orilẹede Libya.

Alabojuto ọfiisi ajọ NEMA to wa ni ipinlẹ Eko, Alhaji Idris Muhammed lo gba alejo awọn abọde Libya naa ni papak ofurufu Murtala Muhammed, Ikeja ni nkan bii agogo mẹta abọ oru ọjọru.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸtàn ni àwọn ọ̀rẹ́ fi ń tan èèyàn lọ si Libya pé iṣẹ́ gidi wà níbẹ̀

Ọgọrun ninu awọn atipo naa jẹ obinrin ti mẹrin ninu wọn jẹ aboyun, mejilelgọta si ni ọkunrin. Gbogbo wọn jẹ agbalagba obinrin mejilelọgọrin, ọmdebinrin mẹtala, ikoko obinri marun un; ati aadọta ọkunrin agbalagba, ọmdekunrin mrin ati ikoko ọmọkunrin mẹtala. Ninu wọn si ni eniyan meji to ni iṣoro ilera wa.

Image copyright NEMA
Àkọlé àwòrán Awọn Naijiria nilẹ Libya

Alabojuto ajọ NEMA nilu Eko gba awọn eniyan to ba n gbero lati rin iru irinajo na aitọ bayii lati yẹra fun un.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDay 17: Àwọn olórí tó wà ní Kwara ń ṣe fún ara wọn nìkan ni #BBCNigeria2019

O ni bi eeyan ba fẹ ṣi lọ si ilu miiran paapaa nilẹ okeere, ilana to tọwa lati tẹle ninu iwe ti yoo da abo bo wọn lọwọ ewu.

O ni iwa ti awọn to n ṣi lọ si orilede mii lọna aitọ yii n kọ awọn tọrọ kan lominu.

Image copyright NEMA
Àkọlé àwòrán Awọn Naijiria nilẹ Libya

Ẹwẹ, o ni fun awọn to ti baba ha sinu panpẹ yii, wn ti ṣeto baalu ti yoo da wọn pada sile. Eto naa ni wọn ni o bẹrẹ ninu oṣu kẹrin ọdun 2017 ti yoo si wa sopin ninu oṣu kẹrin ọdun 2020.