Nigeria 2019 Elections: Èwo nínú ìlérí tí Buhari ṣe ní 2015 ló ti mú ṣẹ?

Aare Muhammadu Buhari Image copyright AFP

Lasiko eto ipolongo ibo aarẹ lọdun 2014 si 2015 ṣaaju eto idibo gbogboogbo to waye lọdun 2015, Aarẹ Muhammadu Buhari ṣeleri awọn nkan ti iṣakoso rẹ yoo ṣe fun araalu ti wọn ba fi dibo yan an sipo aarẹ Naijiria.

Ọpọlọpọ ileri ati ẹjẹ ni Buhari jẹ nigba naa ninu akọsilẹ to pe ni ''Majẹmu mi pẹlu awọn ọmọ Naijiria.''

Laipẹ yii ni aarẹ Buhari sọ nibi eto ipolongo ibo to ṣe ni ipinlẹ Imo ati Abia fun saa keji nipo sọ pe oun ti mu gbogbo ileri t'oun ṣe lọdun 2015 ṣẹ fun awọn ọmọ Naijiria.

A ṣe agbeyẹwo diẹ lara awọn ileri naa.

Igbeaye Irọrun

Ileri to ṣe: Idasilẹ eto fifun awọn ọmọ ileewe alakọbẹrẹ ni ounjẹ ọfẹ

Eto yii jẹ ọkan lara eto oni ẹẹdẹgbẹta biliọnu Naira ti iṣakoso Buhari jẹjẹ fun igbeaye idẹrun fun araalu.

Wọn ni fifun awọn ọmọ ileewe alakọbẹrẹ bi miiọnu mẹẹdogun ni ounjẹ ọfẹ yoo mu idagbasoke ba ipese ounjẹ, ti yoo si tun pese iṣẹ.

Ileri: Idasilẹ eto iranlọwọ owo fun awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ

Eto Ilera

Ileri: O sọ pe oun yoo ri i daju pe ọmọ Naijiria ko ni idi kankan lati lọ gba iwosan nilẹ okeere.

Ipese Iṣẹ

Ileri: Mimojuto idasilẹ miliọnu mẹta iṣẹ lọdun kan nipa dida ileeṣẹ silẹ, iṣẹ ijọba ati fifẹ iṣẹ agbẹ l'oju si i.

Eto aabo

Ileri: Riri daju pe 'ipa tabi agbara kankan labẹle tabi llyin odi ridi joko ni Naijiria.

Paapa gbigbogun ti igbesunmọmi.

Iwa Ibajẹ

Ileri: Lati ṣiṣẹ pẹlu ile aṣofin apapọ lati ṣe ofin eto 'olofofo' whistle blower

Eto naa wa fun ṣiṣe koriya fun ẹnikẹni to ba mọ ohunkohun nipa iwa ti ko tọ lawujọ lati fito awọn alaṣẹ leti.

Fun 'ofofo' to ba jẹ mọ iwa ibajẹ, ẹni to ba tu aṣiri ọrọ naa yoo gba ida meji ataabọ owo ti ijọba ba ri gba.

Owo ti wọn fi n ṣe iṣakoso

Ileri:Lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ile aṣofin lati mu adinku ba iye owo ti wọn fi n gbọ bukata iṣakoso.

Ipese ina mọna-mọna

Ileri: Iṣakoso ẹgbẹ oṣelu APC yoo ri daju pe ipese ina mọna-mọna dara si ti yoo to ogoji ẹgbẹrun laarin ọdun mẹẹrin si mẹjọ.