Atiku: Màá foríji àwọn tó bá dá owó ìlú tí wọ́n kó jẹ padà

Atiku Abubakar ati Obi nibi ipade itagbangba Image copyright Facebook/@PeterObi

Oludije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar ti sọ pe oun yoo dariji awọn to ba ko owo ilu jẹ, ti oun ba fi di aarẹ Naijiria ninu eto idibo to n bọ.

Atiku sọ ọrọ naa nibi ipade itagbangba ti ajọ MAcArthur Foundation, ileeṣẹ amohunmaworan NTA ati Daria media pawọpọ ṣe nilu Abuja.

Nibi ipade naa, Atiku sọ pe oun yoo dariji awọn ti ọwọ ba tẹ pe o wu iwa ibajẹ niwọn igba ti wọn ba ṣetan lati fi iru owo bẹẹ da iṣẹ́ silẹ l'orilẹede Naijiria, ti eto idariji ọhun yoo si ṣe iwuri fun awọn to n kowo ilu jẹ lati finufindọ da a pada lara owo ilu ti wọn ko jẹ pada.

Igbakeji Atiku, Peter Obi naa to da si ọrọ naa, sọ pe eto naa kii ṣe idariji nikan, o ni eyi yoo ran ijọba lọwọ̀ lati tete ri owo ilu ti wọn ji gba pada.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYPP, ADC, PPC ni tòótọ́ ni pé ọmọ oninakuna nijọba Eko lasiko yii

Ẹwẹ, Atiku sọ pe iṣakoso oun yoo ri i daju pe opin de ba bi awọn ọmọ ogun ṣe n padanu ẹmi wọn, ati nkan ijagun si ọwọ̀ awọn agbesunmọmi.

Lori ẹsun kan to sọ pe ọkan lara awọn iyawo rẹ, Jennifer Douglas ṣe mago-mago owo nilẹ Amẹrika, Atiku sọ pe ''Ko ti i si ẹnikẹni to sọ ẹsun naa ni gbangba, bẹẹni wọn ko ti i gbe iyawo mi lọ sile ẹjọ, nitori naa, ẹ ko le fidirẹmulẹ pe lootọ lo ṣe bẹ, nitori pe o ti rinrinajo lọ silẹ amẹrika laimọye igba."

Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ boya yoo fọwọ wọnu to ba fidirẹmi ninu eto idibo sipo aarẹ, Atiku sọ pe nkan to le mu oun ṣe bẹ ni ti 'eto idibo naa ko ba ni mago-mago ninu.'

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí