Àtúpalẹ̀ ìlànà bí Atiku ṣe fẹ́ kojú ìwà ìbàjẹ́

Atiku Image copyright Atiku Abubakar/Twitter
Àkọlé àwòrán Awọn orilẹede bi i Turkey ati Malaysia n lo iru ilana ti Atiku Abubakar fẹ ẹ gba gbogun ti iwa ibajẹ.

Oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar sọ pe oun yoo dari ji awọn to ba ko owo orilẹede Naijiria jẹ, niwọn igba ti wọn ba gba lati da owo naa pada tabi fi da ileeṣẹ silẹ ni Naijiria.

Ọjọru ni Abubakar sọ ọrọ naa nibi ipade itagbangba kan ti ajọ MAcArthur Foundation, ileeṣẹ amohunmaworan NTA ati Daria media pawọpọ ṣe nilu Abuja fun awọn oludije fun ipo aarẹ ati igbakeji wọn.

Atiku: Màá foríji àwọn tó kówó ìlú jẹ́ tí mo bá di àárẹ

‘Ìjọba kò tẹ̀lẹ́ ìlànà òfin lòrí ọ̀rọ̀ Onnoghen’

Ṣugbọn ṣa, kini ilana ti Atiku fẹ lo lati gbogun ti iwa ibajẹ tumọ si?

Onwoye nipa bi nkan ṣe n lọ ni agbo oṣelu Naijiria, to tun jẹ olupolongo tako iwa ibajẹ ninu ajọ Children Anti-corruption Initiative, Akinwande Ọmọlolu ṣe atupalẹ rẹ.

"O dara ti Atiku Abubakar ba le se bẹẹ."

O ṣalaye pe oun ti o tumọ si ni pe awọn to ti kowo ilu jẹ tẹlẹ yoo da a pada fun ijọba, ti ijọba yoo si na owo naa sori eto ọrọ aje Naijiria.

Eyi dara ju ki ijọba o maa gbe wọn lọ sile ẹjọ lọ. Gẹgẹ bi ẹni to n polongo tako iwa ibajẹ, bi eto idajọ wa ṣe ri ko jẹ ki igbogun ti iwa ibajẹ o ṣaṣeyọri.

"O san ki ijọba ba iru ẹni bẹẹ duna-dura lati da owo naa pada, niwọn igba ti awọn miiran ko ni ko owo jẹ mọ, de bi ti iru eto bẹ yoo tẹsiwaju.

Ọna ti ijọba le gba yanju eyi ni lati ṣe ofin pe ki gbogbo awọn osisẹ ijọba to fi mọ awọn to di ipo oṣelu mu lati maa kede dukia wọn, ki wọn to de ipo. Ayẹwo si gbọdọ maa waye lọdun maarun maarun lori awọn dukia bẹ ẹ".

O tẹsiwaju wi pe "Mo gbagbọ pe a ko fi bẹẹ tẹle ofin to de awọn to di ipo iṣakoso mu ni Naijiria. Ijọba si le ṣe idasilẹ oju opo ti wọn o maa fi iru awọn nkan bẹẹ to araalu leti.

Yoo mu ko soro fun wọn lati maa ko dukia jọ. Awọn ọmọ Naijiria yoo si le jẹ oye oju lalakan fi n sọri. Aarẹ Buhari ko ṣe to ninu igbogun ti iwa ibajẹ. Amọ o ṣeni laanu pe afojusun rẹ ti yẹ."

Ko buru ti a ba dan ilana ti Atiku fẹ ẹ gba gbogun ti iwajẹ wo, ka wo esi ti yoo fun wa.

Ṣiṣe bẹ yoo ran ijọba lọwọ lati mọ iwọn dukia ti owo oṣu oṣiṣẹ kọọkan le ko jọ fun un. Ni Akinwande Ọmọlolu wi.

"Igbesẹ ti Atiku fẹ gbe yii lo dara fun Naijiria."

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari gbe iru igbesẹ pe ki awọn to di ipo iṣakoso mu o maa kede dukia wọn, nigba to kọkọ de ipo.

Kini awọn ọmọ Naijria n sọ lori ipinnu Atiku?

Awọn ọmọ Naijiria loju opo Facebook BBC Yoruba kan gbagbọ pe ki Atiku kọkọ ko owo ilu to wa lọwọ rẹ silẹ naa, ko to gbe igbesẹ naa.

Bakan naa ni awọn kan ni ọna to dara ni Atiku fẹ tọ̀ lati gbogun ti iwa ibajẹ.

Awọn orilẹede bi i Turkey ati Malaysia n lo iru ilana ti Atiku Abubakar fẹ gba gbogun ti iwa ibajẹ.