Awọn afọju yoo dibo
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nigeria 2019 Elections: Mílíọ̀nù kan àwọn tó ní ìpèníjà ojú ni yóò dìbò

Bi idibo gbogbo orilẹede Naijiria ọdun yii ti n kan ilẹkun, o le ni miliọnu kan awọn to ni ipenija oju ti wọn yoo kopa ninu eto idibo to n bọ.

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria INEC ti ṣeto ohun elo ti awọn akanda ẹda to ni ipenija oju yoo lo lati fi dibo.

Koda ẹgbẹ awọn to ni ipenija ni Naijiria dunu si igbesẹ lati pese ohun elo idibo fawọn to ni ipenija oju.

Image copyright Facebook/Victor Otuya
Àkọlé àwòrán Idibo ọdun 2019