Ẹjọ́ Walter Onnoghen: NJC nìkan ló lásẹ láti yọ Adájọ́ Ágbá

ONNOGHEN
Àkọlé àwòrán Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti fi ọwọ́ òsì di ẹjọ́ tí Adájọ́ Àgbà lórílẹèdè Naijiria pè mọ́ ìjọba àpàpọ̀.

Adajọ fẹhinti lorilẹede Naijiria, Ret.Justice Folaranmi Oloyede ti ni ijọba apapọ ko bọwọ fun eto idajọ orilẹede Naijiria to ba ilana ati ofin mu.

Adajọ oloyede nigba to n ba BBC sọrọ, wi pe Ajọ to n bojuto eto idajọ lorilẹede Naijiria (National Judicial Council) nikan lo lasẹ lati parọwa si Aarẹ orilẹede Naijiria lati kowe lọ gbe ile rẹ abi ki o lọ rọkun nile fun Adajo Agba lẹyin ti wọn ba ti se iwadii to fihan pe, o jẹbi ẹsun iwa ibajẹ.

Image copyright Twitter

O fikun wi pe, NJC lo ma a fi lẹta ransẹ si ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ iwa ibajẹ,Code of Conduct Tribunal lati le se iwadii ẹsun ti wọn fi kan an.

Lẹyin naa ni Aarẹ yoo gbe imọran naa lọ si Ile Igbimo Asofin Agba, nibi ti awọn asofin yoo ti dibo lati yọ Adajọ Agba naa kuro.

Adajọ fẹyinti Oloyede naa fikun wi pe, lẹyin igbesẹ wọnyii nikan ni aarẹ le yọ Adajo Agba kuro ni ipo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionHubert Ogunde ló m'órí mi yá láti di òṣèré

Lori idajọ ti ile ẹjọ kọtẹmilọrun ti da ẹjọ ti Onnoghen pe nu, adajọ fẹyinti naa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun ni asẹ lati da ẹjọ rẹ nu nitori wi pe Ajọ CCT naa ni asẹ lati gbọ ẹjọ rẹ.

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn da ẹjọ́ Walter Onnoghen nù!

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ti da ẹjọ ti Adajọ Agba Walter Onnoghen pe tako ijọba apapọ.

Onnoghen pe ẹjọ lati tako igbesẹ ijọba to fi ọwọ osi juwe ile fun titi wọn yoo fi gbọ idajọ lori iwa ibajẹ ti wọn fi kan an ati lati tako ile ẹjọ to n gbẹjọ iwa ibajẹ(CCT) lati ma se gbọ ẹjọ rẹ.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun nigba to n da ẹjọ ni dandan Adajọ Agba naa gbọdọ lọ jẹjọ iwa ibajẹ.

Ile ẹjọ naa ni Onnoghen ko ni awijare to le mu ki ile ẹjọ naa sọ wi pe ko ma se jẹjọ, nitori wi pe ko si ẹni to kọja ofin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionDay 17: Àwọn olórí tó wà ní Kwara ń ṣe fún ara wọn nìkan ni #BBCNigeria2019

Idajọ naa tumọ si wi pe ile ẹjo to n gbọ ẹsun lori iwa ibajẹ le tẹsiwaju lati gbọ ẹjọ iwa ibajẹ ti wọn fi kan Adajọ Agba Walter Onnoghen.