Ààrẹ Gani Adams: Olùdíje tó bá ṣetán lórí àtúntò ìlànà ìṣèjọba ni Yorùbá yóò dìbò fún

Iba Gani Adams
Àkọlé àwòrán Gani Adams ní pẹ̀lú bí nǹkan ṣe rí báyìí àtúntò ìlànà ìṣèjọba ti di pàtàkì fún ìlọsíwájú Nàìjíríà

Aarẹ Ọna kakanfi ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti ṣalaye wi pe irufẹ aarẹ ti ilẹ Yoruba yoo dibo fun ni eyikeyi ninu awọn oludije fun ipo aarẹ to ba ṣetan lati mu atunto ilana iṣejọba (Restructuring) lọkunkundun.

Iba Gani Adams ni ohun to n ṣẹlẹ lẹnu oṣelu ati iṣejọba lorilẹede Naijiria bayii fihan pe pataki ni atunto ilana iṣejọba ki gbogbo ẹya ati ede lee tubọ ni ipin to yẹ ninu eto Naijiria gbogbo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀nà tí àwọn olùdíje ipò gómínà ní Ìpínlẹ̀ Ọyọ fẹ̀ gbà yànjú ọ̀rọ̀ ààbò rèé

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Iba Gani Adams ni oun ko lee sọ pe oloṣelu bayii ni yoo ṣe daradara tabi omiran ṣugbọn "ohun kan ti mo lee sọ ni pe eyikeyi ninu wọn to ba daju pe yoo ṣe atunto ilana iṣejsba ni ki Yoruba dibo fun."

Awọn ẹgbẹ ọmọbibi Yoruba bii Afẹnifẹre ati ẹgbẹ agba Yoruba ni wọn ti pin lori oludije ipo aarẹ ti ilẹ Yoruba yoo tẹle. Bi Afẹnifẹre ṣe n sọ pe Atiku lawọn yoo tẹle ni ẹgbẹ agb Yoruba pẹlu n fi atilẹyin wọn han fun Aarẹ Buhari.

Iba Gani Adams ni lootọ ipo oun gẹgẹ bii aarẹ ilẹ Yoruba ko faye oṣelu silẹ, sibẹ ohun ti yoo san ilẹ Yoruba ati awọn eeyan rẹ ni oun yoo maa le lẹka ọmọniyan gbogbo.