2019 elections: INEC ní káàdì ìdìbò 15,000 táwọn ọ̀daran jó ní iléeṣẹ́ INEC kò leè dáwọ́ ìdìbò dúró

Oṣiṣẹ INEC kan n wo iwe idibo wo ni ileeṣẹ ajọ naa kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìwé orúkọ olùdìbò àti káàdì ìdìbò ni wọ́n jó ní iléeṣẹ́ àjọ INEC kan ní ìpínlẹ̀ Abia.

Awọn eeyan kan ti dana sun ọpọlọpọ kaadi idibo to to ẹgbẹrun marundinlogun ni iye nileeṣẹ ajọ INEC to wa ni ipinlẹ Abia.

Gẹgẹ bii awọn alaṣẹ ajọ eleto idibo INEC lagbegbe naa ṣe sọ, awọn kaadi idibo ti wọn dana sun naa ni awọn ti o ku ti awọn oludibo to ni wọn ko tii wa gba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ààrẹ ní kí wọ́n wádìí oun tó fa ìjàmbá bààlú Osinbajo

Ààrẹ Gani Adams sọ ẹni tí Yorùbá yóò dìbò fún ní ọdun 2019 #BBCNigeria2019

Àkójọpọ̀ àwòrán láti ìpàdé ìtagbangba pẹ̀lú àwọn olùdije ní Ọyọ

Iṣẹlẹ yii waye ni owurọ ọjọ aiku.

Bakan naa lawọn leṣebi-leṣeka ẹda naa tun dana sun iwe orukọ awọn oludibo nibẹ.

Image copyright INEC
Àkọlé àwòrán INEC ni ko sibẹru nitori iṣẹlẹ naa

Kọmiṣọna feto idibo nipinlẹ Abia, Joseph Iloh fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin lọjọ aiku. O ni oju ferese lawọn omiṣẹ ibi naa gba wọle.

O ni lootọ awọn eeyan yii jo iwe orukọ ati kaadi idibo awọn oludibo nibẹ ṣugbọn ojulowo iwe orukọ oludibo wa ni olu ileeṣẹ ajọ naa to wa ni ilu Umuahia.

Nibayii naa, awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori awọn to wa nidi iṣẹ ibi naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀nà tí àwọn olùdíje ipò gómínà ní Ìpínlẹ̀ Ọyọ fẹ̀ gbà yànjú ọ̀rọ̀ ààbò rèé