Lagos Impeachment: Tinubu parí aáws Ambode àtàwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ Eko

Tinubu ati Ambode lẹyin ipade naa
Àkọlé àwòrán Ó ti tó bí ọ̀sẹ̀ díẹ̀ báyìí tí awuyewuye láàárín gómìnà Ambọde àtàwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ Eko ti ń jà rànyìnrànyìn ní ìgboro

O ṣeeṣe ki gbun-gbun-gbun to wa laaarin gomina ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambọde atawọn aṣofin ipinlẹ Eko, eleyi to ti n mu ariwo iyọnipo gomina naa kari aye o pari bayii lẹyin ti aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC lorilẹede Naijiria, Bọla Tinubu da sii.

Nibi ipade kan eyi ti gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa ṣe pẹlawọn aṣofin naa ati gomina Ambọde pẹlawọn eekan ẹgbẹ oṣẹlu APC nipinlẹ Eko, GAC ni iroyin sọ pe wọn ti yanju aawọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ to ba awọn oniroyin ss lẹyin ipade naa, Tinubu ṣalaye pe, 'loots ni edeaiyede ti n waye laarin ẹka iṣejọba mejeeji yii lati nnkan bii ọsẹ kan bayii.

"A gbe ẹdun ọkan igun mejeeji yi yẹwo. Gẹgẹ bii aṣiwaju, a tun gbe awọn agbegbe ti o yẹ ki awọn mejeeji o ti bu omi suuru mu. Lọna ati gbe eto iṣejsba ro, a ni lati ṣe ohun gbogbo to tọ.

Ko si ohun to jọ yiyọ ẹnikẹni nipo. O yẹ ki ibaraẹnisọrọ to loorin o wa gẹgẹ bii ara eroja eto iṣejọba tiwa-n-tiwa."

Àkọlé àwòrán Tinubu ni ko sọrọ mọ lori yiyọ Ambọde nipo

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni Tinubu, aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC lẹkun aringbungbun ipinlẹ Eko, Ọmọba Tajudeen Olusi, Gomina Ambode, Igbakeji rẹ, Adebule, olori ile aṣofin ipinlẹ Eko Mudashiru Obasa, ati igbakeji rẹ, Wasiu Esinlokun.

Bakan naa ni oludije fun ipo gomina lẹgbẹ Oṣelu APC nipinlẹ Eko Babajide Sanwo-Olu ati igbakeji rẹ, Fẹmi Hamzat naa wa nibẹ pẹlu.