Ìtàn Mánigbàgbé: Lára àwọn ọmọ-ọmọ Ajayi Crowther ni Herbert Macaulay

Samuel Ajayi Crowther Image copyright @BAMEAnglican

Kii se igba akọkọ ree ti a gbọ orukọ Bisọọbu Samuel Ajayi Crowther nilẹ Yoruba ati ni orilẹede wa Naijiria lapapọ.

Odu ni, kii se aimọ fun oloko paapa ninu itan ẹsin awọn ọmọlẹyin Kristi ni orilẹede Naijiria ati iwa imunilẹru jake-jado agbaye.

Ogbontagi ọmọ Oodua to gbe ogo ilẹ adulawọ ga ni, ko si yẹ ka ma mọ itan igbesi aye rẹ, ati ọgbọn ta lee ri kọ ninu rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Image copyright @BAMEAnglican

Gẹgẹ bi a ti se akojọpọ itan igbe aye Samuel Ajayi Crowther lori itakun agbaye, ololufẹ oniruuru ede ni, to si kọ ẹkọ nipa ede to to mẹrin.

Awọn ohun to yẹ ko mọ nipa Samuel Ajayi Crowther:

 • Ọdun 1809 ni wọn bi Ajayi sile aye silu Osogun to wa lẹba ilu Isẹyin nipinlẹ Ọyọ
 • Idile Alaafin Abiọdun ni iya Ajayi, ta si lee pe ni ọmọọba
 • Ọmọ ọdun mejila ni Ajayi lasiko ti awọn ọmọ ogun Fulani ko ni ẹru lọdun 1891, ti wọn si ta fawọn eebo pọtugi to n sowo ẹru
 • Ṣugbọn oriire Ajayi gbe ko alawore, nigba ti awọn ọmọ ogun oju omi ilẹ Gẹẹsi, to n gbogun ti owo ẹru ṣiṣe gba ọkọ oju omi rẹ silẹ, ti wọn si gbe Ajayi lọ si ilu Freetown, lorilẹede Sierre Leone, nibẹ si lo ti gba idande kuro ni ipo ẹru, to si ni ominira rẹ pada
 • Ọwọ ẹgbẹ CMS ti ijọ Anglican ni Ajayi bọ si ni Sierra Leone, ti wọn si kọ ni ede oyinbo, bẹẹ lo di ẹlẹsin Kristi pẹlu
 • Ọjọ Kọkanla, osu Kejila ọdun 1825 ni Ajayi se iribọmi, ti wọn si mu lọ silẹ Gẹẹsi lati lọ jọsin, ko si tun lọ sile iwe
 • O yi orukọ rẹ pada si orukọ adari ijọ Christ Church to wa ni London, to tun jẹ ọkan lara awọn oludasilẹ ẹgbẹ CMS, eyi tii se Samuel Crowther. Orukọ naa si ni Ajayi n jẹ titi ti ọlọjọ fi de si
 • O pada si ilu Freetown lọdun 1827, oun si ni akẹkọ akọkọ ti yoo lọ sile ẹkọ Fourah Bay College, to si n sisẹ olukọ lẹyin to pari ẹkọ rẹ tan
 • Ajayi nifẹ lati gbọ oniruuru ede, idi niyi to fi kọ ẹkọ ede Latin, Greek ati Temme
 • Musulumi ati olukọ ni iyawo Ajayi, tii orukọ rẹ n jẹ Asano abi Hassana, wọn ko oun naa lẹru ni, ki wọn to gba silẹ wa si Freetown. Amọ wọn se itẹbọmi fun, to si yipada di Kristiẹni, orukọ rẹ si n jẹ Susan
 • Lara awọn ọmọ ti Ọba Oke fi jinki Samuel Ajayi Crowther ni Dandeson Coates Crowther, tii se Bisọọbu agba fun agbegbe Niger Delta, Abigail Crowther, ẹni to fẹ Thomas Babington Macaulay, tii se baba Herbert Macaulay. Eyi tumọ si pe ọmọ ọmọ Samuel Ajayi Crowther ni Herbery Macaulay, tii se ajijagbara laye eebo amunisin, jẹ
 • Ajayi di ojisẹ Ọlọrun, ti wọn si yan bii Bisọọbu ilu London. O pada si ilẹ Afrika lọdun 1843 pẹlu Henry Townsend, to da ijọ ẹlẹsin Kristi silẹ nilu Abẹokuta nipinlẹ Ogun.
 • Ajayi lo tumọ bibeli ni ede oyinbo si Yoruba, eyi to pe ni Iwe Mimọ Bibeli, to si tun se akojọpọ iwe atumọ ede (Dictionary) ni Yoruba, to si tun kọ oniruuru iwe sita, to fi mọ akojọpọ awọn owe ilẹ Kaarọ oo jire to gbe jade lọdun 1852
 • Ajayi gbe ile kan ti Henry Townsend kọ silu Badagry lọdun 1845 fun ọpọlọpọ ọdun, to si tun gbe iwe jade lede Igbo ati Nupe lọdun 1864
 • Aisan rọlapa-rọlẹsẹ, ta mọ si stroke, lo gbẹmi Samuel Ajayi Crowther lọjọ kọkanlelọgbọn osu Kejila ọdun 1891, ti wọn si sin si itẹ oku Ajẹlẹ nilu Eko.

O yẹ ki gbogbo wa ri ọgbọn kọ ninu itan igbe aye akọni ọmọ Oodua yii, ẹni to jẹ ẹru, amọ to ta ara rẹ yọ.

Ipokipo ti a ba wa, o yẹ ka maa ri daju pe a sa ipa wa, lati fi ọgbọn ori wa han, ka si se iwọn ti a lee se.