BBC Nigeria 2019: Àwọn èèkàn ọmọ Ogun nínú ìṣèjọba Nàìjíríà.

Àwọn èèkàn ìṣèjọba Nàìjíríà Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn èèkàn ìṣèjọba Nàìjíríà

Ninu oṣelu ati iṣejọba Naijiria, ọpọlọpọ ni awọn eekan to kara jọ sibẹ to jẹ wi pe bi wọn ba wi, kii pẹ tan kalẹ gẹgẹ bi iroyin, pupọ ninu wọn si wa lati ipinlẹ Ogun.

Bi a ba tun wa fi ti ẹya tabi ede wo o, awọn ọmọ Yoruba wọnyii kii ṣe ẹni aa fọwọ rọ sẹyin ni awọn ibi giga giga lorilẹede Naijiria.

Ki Naijiria to gba ominira ati lẹyin ominira ni a ti ri awọn wọnyii to n le waju ninu iṣakoso ati idari loniruuru ọna. Ẹwẹ, awọn to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun ni a o gbeyẹwo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Bukola Saraki ni adari wa' - Razaq Atunwa, Kwara

Oluṣẹgun Arẹmu Ọbasanjọ

Ọjọ karun un oṣu kẹta ọdun 1937 ni a bi Oloye Oluṣẹgun Mathew Okikiọla Arẹmu Ọbasanjọ (GCFR, PhD) ni ilu Abeokuta, ipinlẹ Ogun. Ọgagun tẹlẹ ri lo jẹ ni ile iṣẹ ogun Naijiria ko to di olori orilẹede labẹ ijọba ologun laarin ọdun 1976 si 1979 lẹyin naa lo tun di olori orilẹede labẹ ijọba atiwa n tiwa laarin ọdun 1999 si 2007 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party.

Ọbasanjọ rinrin ajo pupọ lọ soke okun to si ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu awọn ajọ ilẹ okere ti inu awọn naa si dun lati ni ba ọmọ ilẹ adulawọ bayii dọrẹ eyi ti ko kọ esi ọrọ ẹnikẹni si igbesẹ rẹ yala nile tabi lẹyin odi ti Ọbasanjọ a si maa bori iru ẹnu atẹ wọnyii lọpọ igba.

Ọjọ kọkandilọgbọn tii ṣe ọjọ ti Oluṣẹgun Ọbasanjọ di aarẹ alagbada ni wọn lo gẹgẹ bi ayajọ ọjọ ijọba tiwa n tiwa bayii lorilẹede Naijiria.

2003 ni wn tun dibo yan Ọbasanjọ eyi to si jẹ idibo pẹlu ọpọlọpọ iwa ipa ati ipenija. Nigba naa lọhun Ọgagun Muhammadu Buhari ni oludije ẹgbẹ alatako ṣugbọn Ọbasanjo jawe olubori.

Nigba ti ipinnu rẹ lati lo saa kẹta lori alefa gẹgẹ bi aarẹ ko rọwọ mu ni o gbe eku ida kalẹ lẹyin idibodun 2007.

Ọbafẹmi Awolọwọ

Oloye Ọbafẹmi Jeremiah Oyeniyi Awolọwọ (GCFR) jẹ ọmọ bibi ilu Ikenne ipinlẹ Ogun lọjọ kẹfa oṣu kẹta ọdun 1909 o si di oloogbe lọjọ kẹsan oṣu karun ọdun 1987. O jẹ agba orilẹede Naijiria ti gbogbo eniyan bọwọ fun nitori iṣẹ takuntakun rẹ ninu igbesẹ lati gba ominira fun Naijiria - lasiko ijọba amunisin to di mọ lasiko ogun. Oloṣelu nla ni pẹlu. Oun ni awọn mọ si oludasilẹ akọkọ ti Western Union o si tun jẹ Kọmisana fun eto isuna. Bakan naa, o ti jẹ igbakeji aarẹ fun igbimọ alaṣẹ orilẹede yii.

Awolọwọ lo ṣe iṣẹ ọpọlọpọ iṣofin eyi to ti sọ Najiria di ilu olokiki bayii. Wọn maa n ri Awolọwọ gẹgẹ bii aṣaju eto oṣelu ijọba awa ara wa. O ṣe eto ẹk ọfẹ fun gbogbo gbo ati ilera ọfẹ fawọn ọmọde lẹkun Iwọ Oorun. Oun lo kọkọ da ile iṣẹ mohunmaworan akọkọ silẹ nilẹ Afirika lọdun 1959.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#BBCGovDebate: Olùdíje 5 ni yóò kópa nínú ìpàdé ìtagbangba l‘Ogun

Funmilayọ Ransome-Kuti (MON)

Oloye Funmilayọ Anikulapo-Kuti jẹ ọmọ bibi ilu Abeokuta lọjọ kẹẹdgbọn oṣu kẹwa ọdun 1900 titi to fi papoda ni ọjọ kẹtala oṣu kẹrin ọdun 1978. Oluk ni o jẹ, olupolongo oṣelu, ajafẹt obinrin ati onigbagbọ ninu aṣa. O jẹ kan lara awn aṣaju orilẹede Naijiria nigba aye rẹ. Oun naa si ni obinrin akọkọ to kọkọ wa ọkọ. Ilakaka rẹ ninu oṣelu lo mu ki wn maa sapejuwe rẹ gẹgẹ bi ''Erelu ẹtọ awọn obinrin lorilẹede Naijiria''. Wọ́n tun maa n pe e ni Iya Afirika. Afihan agbara rẹ ninu jija fẹtọ pọ to bẹẹ ti wọn tun ṣapejuwe rẹ lọdun 1947 bi ''Kiniunbinrin ti Lisabi'' fun idari rẹ lori awọn obinrin Ẹgba nipa bi wọn ṣe bere owo ori gọbọi lọwọ wọn. Funmi Kuti ni iya to bi gbajugbaja olorin ajafẹtọ ọmọniyan, Fela Anikulapo Kuti.

Ọladipọ Diya

Ilu Odogbolu ni ipinlẹ Ogun ni a ti bi Donaldson Ọladipọ Diya ni ọj kẹta oṣu kẹrin ọdun 1944. Diya jẹ onimọ nipa ofin tro si jẹ adajọ ile ẹjọ to ga ju lọ lorilẹede Naijiria o si tun kẹkọọ nipa iṣẹ ogun.

Wọn yan an gẹgẹ bii gomina ijọba ologun ti ipinlẹ Ogun laarin 1984 si ọdun 1985. O ti jẹ ọgagun lori oriṣiriṣi ikọ ogun lorilẹede Naijiria. Wọn yan an ni Ọga agba awọn ọm ogun alaabo lọdun 1993.

Lọdun 1997, Wọn fi ẹsun kan pe Diya pẹlu awọn ọmọ ogun rẹ lati gba ijọba lọwọ ijọba Sani Abacha nigba naa ṣugbọn awn to nifẹ si iṣejba Abacha tu aṣiri igbesẹ naa wọn si ju Diya atawọn ikọ rẹ sẹwọn.

Yẹmi Ọṣinbajo

Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo jẹ ọmọ bib ilu Ikenne ni ipinlẹ Ogun. Wọn bi i ni ọjọ kẹjọ oṣu kẹta ọdun 1957. O di igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria lọjọ kkandinlọgbọn oṣu karun ọdun 2015 oun si tun ni igbakeji fun aarẹ Buhari ninu idije fun ipo aarẹ Naijiria lọdun 2019. O jẹ amofin agba orilẹede Naijiria. O ti jẹ kọmisana fun eto idajọ ni ipinlẹ Eko ri fun ọdun mẹjọ.

O jẹ oluṣọ aguntan ni ijọ irapada, RCCG.

lati ọdun ti Yẹmi Ọṣinbajo ti dara pọ mọ oṣelu Naijiria, awn eto ati igbesẹ rẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ti n fa oju ọpọ mọra yala lati to si i lẹyin tabi lodi si oun ati isejọba aarẹ to n ṣe igbakeji rẹ.