Bode George dá sí aawọ̀ Buhari, Obasanjo
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

BBC Nigeria 2019: Ọ̀rọ̀ àwọn olóṣèlú, tásìkò bá tó, akólòlò á pe baba - Bode George

O ti pẹ ti ọrọ ti n jẹyọ si gbangba laarin oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ àti aarẹ Muhammadu Buhari, Ni kete ti ọkan ba sọ ni ẹnikeji yoo ti fesi. Gẹgẹ bi agba oloṣelu ti awọn mejeeji jẹ, iwoye yii ni Oloye Bode George fi fi ọrọ agba ba wọn sọrọ nitori Yoruba ni agba la fi n wagba.