Nigeria Elections 2019: Àjọ elétò ìdìbò f'ọjọ kún gbedeke gbígba káàdì ìdìbò

Káàdì ìdìbò alálòpẹ́ Image copyright INEC NIGERIA/FACEBOOK
Àkọlé àwòrán Àjọ elétò kéde ọjọ́ ajé tó mbọ̀ láti gba káàdì ìdìbò

Ajọ eleto idibo orileede Naijireia Inec ti fi kun gbedeke ọjọ ti awọn oludibo yoo lanfani lati gba kaadi idibo wọn pẹlu ọjọ mẹta.

Ọjọ ẹti tii ṣe ọjọ kẹjọ oṣu keji ni wọn ti saaju da lọjọ gbedeke gbigba kaadi yii amọ bayi alaga ajọ naa ọjọgbọn Mahmood Yakubu ni awọn oludibo le gba kaadi naa titi di ọjọ Aje tii ṣe ọjọ kọkanla oṣu keji 2019.

Ojọgbọn Yakubu lọ kede isunsiwaju yi ninu ipade kan ti o ṣe pẹlu awọn adari eto idibo lawọn ipinlẹ lọjọ ẹti.

Inec ni ọjọ abamẹta ati ọjọ aiku yoo kun ọjọ ti awọn eeyan yoo fi gba kaadi naa bẹrẹ laago mẹsan aarọ di ago mẹfa irọlẹ.

Kaadi idibo ọlọjọ pipẹ PVC ni ami idanimọ ti awọn oludibo yoo lo lati fi kopa ninu idibo gbogbogbo 2019 to wole tan.

Eyi kii ṣe igba akọkọ ti ajọ Inec yoo sun gbedeke ọjọ gigba kaadi idibo siwaju-ọjọ kọkanlelogun oṣu kini 2019 ni wọn saaju da ṣugbọn wọn sun siwaju lẹyin ti wn ri pe pupọ ara ilu ni ko ri kaadi naa gba.

Kaadi idibo yi ni wọn fi aworan ati orukọ to fi mọ awọn iroyin miran to ṣe koko nipa oludibo si.Ẹni ti ko ba ni kaadi yi ko ni le dibo bẹẹ si ni eeyan kan ko le fi kaadi elomiran dibo