#2019NigeriaDecides Ìká wò ló lérò wí pé o yẹ láti fí dibo?

Oṣiṣẹ Inec lasiko idibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Oṣiṣẹ Inec n salaye bi awọn oludibo yoo ti ṣe tẹ ika soju iwe idibo

Yoruba bọ wọn ni ika to ba tọ si imu laa fi n remu.

Amọ lasiko idibo gbogboogbo Naijiria ti o ku ọjọ diẹ, ika onikaluku ni ipa ti yoo ko sugbọn kii ṣe wi pe wọn yoo fi re imu.

Ika ni awọn oludibo yoo tẹ lati yan oludije to ba wu ọkan wọn fun ipo kipo ti wọn ba n dije fun.

Àkọlé fídíò,

Ọkọ àti ìyàwó sọ àsọtẹ́lẹ̀ tani yóò wọlé nínú PDP tàbí APC

Bi idibo naa ti ṣe ku ọjọ diẹ, ọrọ ika ti awọn oludibo le lo lati fi dibo ti ko si nii ṣe akoba fun ibo wọn lawọn eeyan n ran lẹnu.

Idi ni pe ti eeyan ko ba tẹ ika rẹ bi o ti ṣe yẹ s'aye ti INEC pese lori iwe idibo, irufẹ ibo bẹẹ ko ni jẹ itẹwọgba, eyi to ja si pe eni naa sọ ibo naa danu.

Àkọlé fídíò,

2019: Wo fídíò bí wọ́n ṣe sọ nǹkan lu àwọn adarí APC l'Abẹokuta

Tori ti awọn ẹgbẹ oṣelu ko fẹ ki ibo awọn sofo, pupọ ninu wọn ti n fi ipolongo sita loju opo Twitter ati ni aye ipolongo ibo fun awọn ọmọ ẹgbẹ wọn nipa ika to yẹ lati fi dibo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ko si ika ti o ko le tẹ, ṣaa tẹẹ daadaa ni

Lara ohun ti wọn n sọ ni pe ika aarin a ma jẹ ki ọda itẹwe ti Inec pese fun ontẹ duro daada si aarin oju aye ẹgbẹ ti oludibo fẹ dibo fun.

Wọn gba awọn oludibo niyanju lati ma ṣe lo atanpako wọn fi dibo.

INEC: Ko si ika ti ẹ ko le lo lati dibo

INEC fi alaye sita nipa awọn igbesẹ ti oludibo yoo gbe lasiko ibo bẹrẹ lati ibi ayẹwo oruko to fi de ori ika titẹ.

Labala ika titẹ, oun ti wọn sọ ni pe ki oludibo fi ika wọn kan ọda itẹwe ki wọn si fi ika ti wọn fi ọda si yii tẹ oju aye ẹgbẹ ti wọn fẹ lori iwe idibo.

Eyikeyi ninu gbogbo ika la le fi dibo.

Àkọlé fídíò,

#BBCNigeria2019: Nnamdi Kanu sọrọ lórí àwọn oludije PDP àti APC

Nigba ti BBC tẹsiwaju lati beere alaye lori ọrọ yii, Ijeoma Igbokwe to jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ Inec lẹka idanilẹkọ nipa idibo sọ pe ko si ika ti eeyan ko le lo lati fi tẹka.

O ni 'ohun to ṣe pataki ni ki oludibo ma jẹ ki ami ika rẹ re kuro laarin alafo ẹgbẹ to fẹ yan si ibo miran.'

Àkọlé fídíò,

Femi Falana: kò yé kí ìdájọ́ òfin yàtó síra wọn ni Naijiria

'Ti ami naa ba ti kọja alafo naa, ibo oludibo bẹẹ ti gbofo ni yẹn.'

Ọjọ kẹrindinlogun ni idibo Aarẹ ati ti awọn asoju ile aṣofin yoo waye jakejado orileede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: