Babachir Lawal: Akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ nígbà kan rí ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn àjẹbánu

Babachir Lawal Image copyright @officialefcc
Àkọlé àwòrán Akọwe ijọba tẹlẹ dero ile ẹjọ

Akọwe ijọba apapọ tẹlẹ ri Babachir Lawal, ti foju ba ile ẹjọ loni ọjọ Iṣẹgun l'Abuja lẹyin ti ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu EFCC ju si atimọle lọjọ Aje.

Ajọ EFCC gbe Ọgbẹni Lawal ati marun un miran lọ ile ẹjọ lori ẹsun onikoko mẹwaa to da lori nina owo to ju ilaji biliọnu kan naira lati fi pa koriko.

Awọn miran ti wọn jọ fẹsun kan ni Hamidu David Lawal, Sulaiman Abubakar, Apeh John Monday, ile iṣẹ Rholavision Engineering Limited ati Josmon Technologies Limited.

Ile ẹjọ giga kan ni Abuja ni wọn gbe e lọ ti o si sọ wipe oun ko jẹbi ẹsun ṣiṣe owo ilu ni kumọkumọ.

EFCC ni, akọwe agba fun ijọba apapọ tẹlẹ ri naa ni ipin tirẹ ti yoo gba ninu iṣẹ to gbe fun ile isẹ Rholavision Engineering Limited ati Josmon Technologies Limited lati ṣe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBBC Nigeria 2019: Lekan Kingkong ní a kò fẹ́ ìtàsílẹ̀ àti ikú ọ̀dọ́ lásìkò ìbò