2019 Elecftions: Ìyàwó Atiku ní dídùn lọsàn yóò so fún ọkọ òun

Titi Abubakar iyawo atiku abubakar
Àkọlé àwòrán Ìyàwó Atiku Abubakar ṣalàyé pé ó dájú pé Atiku Abubakar ni ààrẹ tó kàn lórílẹ̀èdè Nàìjíríà

Iyawo oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, arabinrin Titi Abubakar ti sọ pe ọkọ oun, Atiku Abubakar ni aayo awọn araalu kaakiri orilẹede Naijiria.

Titi Abubakar ṣalaye ọrọ yii, lasiko ti ikọ ipolongo ẹgbẹ oṣelu PDP pẹlu oludije fun ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu naa, balẹ si gbagede Tafawa Balewa Square, TBS nilu Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBBC Nigeria 2019: Lekan Kingkong ní a kò fẹ́ ìtàsílẹ̀ àti ikú ọ̀dọ́ lásìkò ìbò

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Arabinrin Titi Abubakar ni, o da oun loju pe Atiku Abubakar ni yoo bori ibo aarẹ ti yoo waye lọjọ abamẹta jakejado orilẹede Naijiria.

Omilẹgbẹ awọn ero ni wọn ti gunlẹ si gbagede Tafawa Balewa (TBS) lati pade oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu naa, Atiku Abubakar ati ikọ rẹ.

Titi Abubakar tun ṣalaye pe, bi ọkọ oun ba fidirẹmi ninu idibo naa, oun yoo gba fun Ọlọrun lori rẹ.

Àkọlé àwòrán Awọn ero ni gbagede TBS nibi ipolongo PDP

Amọṣa, o ni 'bi gbogbo nnkan ṣe n lọ lasiko ipolongo kaakiri tibu-toro Naijiria, o daju pe Atiku ni yoo di aarẹ Naijiria.'

Awọn adari ẹgbẹ oṣelu PDP miran to tun ba BBC News Yoruba sọrọ pẹlu ni, didun lọsan yoo so fun ẹgbẹ oṣelu naa lọjọ abamẹta.

Wọn fi idaniloju han pe ko sewu fun ilepa Atiku Abubakar lati di aarẹ orilẹede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption2019: Wo fídíò bí wọ́n ṣe sọ nǹkan lu àwọn adarí APC l'Abẹokuta