2019 Elections: APC ní Amosun l‘eku ẹdá ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Buhari l'Abẹokuta

Aarẹ Buhari fa ọwọ oludije ipo gomina nipina Ogun, Dapọ Abiọdun soke nilu Abẹokuta nigbati Amosun naa n woo Image copyright APC
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní àwọn kábámọ̀ ìdójútì ńlá tí àwọn jàǹdùkú náà kó bá Ààrẹ Buhari

Lẹyin yanpọnyanrin to waye nibi ipolongo idibo aarẹ Buhari ati APC nilu Abẹokuta ni ọjọ Aje, ẹgbẹ oṣelu APC ti sọ pe gomina Ibikunle Amosun ko ni lọ lai fara gb'ẹgba sẹria to ba tọ, lati ọdọ awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa.

Okiki kan ni ọjọ Aje nipa ipolongo idibo ti aarẹ Muhammadu Buhari pẹlu ẹgbẹ oṣelu rẹ, iyẹn APC ṣe ni ilu Abẹokuta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Okiki to kan kii ṣe tori pe aarẹ lọ ṣe ipade ipolongo ibo nibẹ nitori omilẹgbẹ irufẹ eto ipolongo ni aarẹ ti gbe ṣe lati igba ti o ti bẹrẹ ilepa fun saa keji gẹgẹ bii aarẹ orilẹede Naijiria.

Amọṣa ohun to mu ki eyi ṣaraọtọ ni ti yanpọnyanrin to waye, iyẹn bi awọn kan ṣe bẹrẹ si ni ju oko atawọn nnkan miran ti ọwọ wọn ba ba, lu awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu naa ninu eyi ti aarẹ paapaa ko gbẹyin nibẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBBC Nigeria 2019: Lekan Kingkong ní a kò fẹ́ ìtàsílẹ̀ àti ikú ọ̀dọ́ lásìkò ìbò

Eleyii ti ko tii ṣẹlẹ rii lati igba ti aarẹ ti bẹrẹ ipolongo rẹ kaakiri orilẹede Naijiria.

Ibeere ti ọpọ n beere bayii ni pe, niwọn igba to jẹ pe gomina Amosun to ni aawọ pẹlawọn eekan ẹgbẹ oṣelu naa kan, lawọn eeyan n tọka si gẹgẹ bii eku ẹda to da rukerudo naa silẹ, ṣe ẹgbẹ yoo da sẹria fun?

Image copyright APC
Àkọlé àwòrán APC ni sẹria to tọ yoo wa fun Amosun

Ninu atẹjade kan ti alukoro ẹgbẹ oṣelu APC, Lanre Issa-Onilu fi sita ni ọjọ Iṣẹgun, ẹgbẹ oṣelu APC "yoo gbe iwa aṣemaṣe naa yẹwo lati gbe igbesẹ to ba yẹ ni kete ti idibo ba pari".

O ni ẹgbẹ APC kabamọ iwa naa, eleyii to ni gomina Amosun ṣe agbatẹru rẹ atipe, ko si aniani kan lori agbara ẹgbẹ oṣelu ati iwa ọmọluabi gẹgẹ bii iwe ofin ẹgbẹ oṣelu APC ti ṣe laa kalẹ fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ lai yọ ẹnikẹni silẹ.