2019 Elections: Ṣé òṣì n pọ̀ si tàbí o n dínkù láwùjọ?

Okunrin to n sa agolo ni akitan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹede Naijiria ni eto ọrọ aje rẹ tobi julọ ni Afrika, oun naa si lo n pese eporọbi julọ.

Ṣugbọn, oun kan naa ni orilẹede nibi ti ilaji awọn to n gbe ninu rẹ si n gbe ninu ìṣẹ́ ati òṣì- ìdá ọgọta ninu wọn ni ko si le gba ile gbigbe to dinwo julọ.

Bakan naa ni awọn to lowo pupọ naa wa, alaafo to si wa laarin olowo ati talaka ko farapamọ rara, gbogbo oju lo n ri ni awọn ilu nlanla to wa ni Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni ipalẹmọ fun eto idibo ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keji, BBC Reality Check ṣe agbayẹwo rẹ boya awọn talaka n talaka si, ati boya alaafo to wa laarin olowo ati talaka n pọ si.

Ariyanjiyan

Ijọba to wa ni iṣakoso n tẹnumọ pe oun ti pa ìṣẹ́ run, to si n di ẹbi ru awọn iṣakoso to kọja pe wọn ṣe aṣilo ileeṣẹ eporọbi ati ọrọ aje.

Ọjọgbọn Ọṣinabajo to jẹ igbakeji aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe ''kii ṣe pe oṣi ti tan patapata o. Nnkan ti mo n sọ ni pe ọrọ ìṣẹ́ ati oṣi la n ba a finra lọwọlọwọ.

Oríṣun àwòrán, AFP

Olori alatako Buhari ninu eto idibo to n bọ, Atiku Atiku Abubakar, sọ pe eto ọrọ aje Naijiria ko buru to boṣe wa bayi ri.

"Ibeere to ṣe koko ju lasiko eto idibo yii ni pe: ṣe igbeaye rẹ dara ju boṣe wa ni dun mẹrin sẹyin, ṣe o lowo si ni tabi o toṣi si?"

Ọrọ̀ aje to wa ninu wahala

Laipẹ yii ni ọrọ aje Naijiria ṣẹṣẹ fi àpẹrẹ ipadabọ sipo han, lẹyin ti didojuru rẹ dopin lọdun 2017.

Akọsilẹ iye awọn ti ko niṣẹ lọwọ ti ileeṣẹ National Bureau of Statistics fi sita ju ìdá ogun lọ.

Akọsilẹ miran tun niyi - bi ìdá ọgọta ni awọn to n gbe ninu òṣì tó pọ̀ - ohun ti wọn fi ṣe odiwọn rẹ ni iye awọn to jẹ pe ile gbigbe, ounjẹ ati aṣọ nikan ni agbara wọn ka.

Botilẹjẹ wi pe ko si akọsilẹ tuntun, awọn onimọ ri i pe igbeaye awọn to toṣi ju ko fi bẹ ẹ dara ju ti tẹlẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Alamy Stock Photo

Àkọlé àwòrán,

Ajọ agbaye woye pe ọpọ awọn to n gbe ni igboro ni orilẹede Naijiria lo n gbe awọn agbegbe ti ko bojumu

Ìṣẹ́ ati oṣi "ko parapọ rara"

Ọpọ̀ lo gbagbọ pe aidọgba n pọ si lojoojumọ.

Onimọ kan, Abdulazeez Musa tilẹ sọ pe ọjọ ti pẹ ti inakuna, iwa ibajẹ ati aibọwọ fun ilana ti wa ni Naijiria, eyi naa si lọwọ si bi ọpọ eniyan ṣe n gbe ninu oṣi.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Sokoto ni awọn to toṣi pọ ju si ni Naijiria

Awọn ipinlẹ to wa ni Ariwa Naijiria ni òṣì pọ si ju awọ̀n to wa ni Gusu lọ.

Ipinlẹ Sokoto to wa ni ẹkùn Iwọ oorun Ariwa ni oṣi pọ si julọ, pẹlu ìdá mọkanlelọgọrin, nigba ti ipinlẹ Eko, ni ẹkun Iwọ oorun Gusu wa ni ìdá mẹrinlelọgbọn.

Ọkan lara awọn oludije fun ipo gomina nipinlẹ Eko, Omolara Adesanya sọ pe ''oṣi to n ba wa finra, ko farapamọ rara.''

Ile gbigbe gẹgẹ bi odiwọn fun oṣi

Bi ilaji awọn to n gbe ni Naijiria lo n gbe ni igboro - ọpọlọpọ awọn ile ti wọn ṣẹṣẹ kọ si awọn adugbo to joju ni gbese ni ilu Eko lo ṣófo, ti awọn adugbo ti ko ri bẹ si kun fọfọ.

Ajọ awọn orilẹede (UN), woye pe ida mọkandinlaadọrin awọn to n gbe ni igboro l'orilẹede Naijiria lo n gbe ni awọn agbegbe to ku diẹ kaato, ti awọn ti ko rile gbe si n lọ si bi miliọnu mejidinlogun.

Ìdá bi ogoji pere ni mọlẹbi to lowo lati gba ile tuntun ti owo rẹ kere ju.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Orilẹede Naijiria wa lara awọn ti eniyan rẹ n pọ si ju lagbaye

Banki agbaye paapa sọ pe orilẹede Naijiria lo ni awọn akuṣẹ julẹ ni agbaye bayii.